![]() |
Salvador |
Opo awon omo egbe oselu PDP nipinle Eko
ti won gbo pe alaga egbe naa Onarebu Moshood Adegoke Salvador ti kede pe oun
ti fegbe naa sile darapo mo egbe oselu APC loro naa si n se ni
kayefi gidi, ohun to si n jade
lenu won ni pe opin ti de ba PDP patapata nipinle naa.
Lati bi osu kan loro
naa ti n ja nile ti wahala ti wa ninu egbe yii, nitori bi won se ni Oloye Bode George to je okan
lara awon agba egbe PDP ti ba nnkan je jinna ninu egbe naa. Lara wahala ti won tun jo n fa a ni
bi won
se loun atawon eeyan e kan fe ran Salvador lewon apapandodo lori isele to waye
ni Eti- Osa nibi ti won ti pa alaga PDP nijoba ibile Apapa, iyen Oloogbe Adeniyi Aborisade.
Ninu oro Salvador lojo naa lo ti so pe
oun ti setan pelu awon ololufee oun ti won to egberun
meeedogun lati darapo mo APC. O so pe oun kabamo pe oun fi egbe naa sile pelu gbogbo wahala ti oun se, sugbon ti won ko je ki oun pari e nitori
awon asaaju ti won ko to asaaju se. O ni egbe naa kun fawon asaaju ti won ko le
saseyori kankan.
Okunrin naa tun salaye pe “Alaga igbimo agba fegbe oselu PDP iyen
BOT ati alaga egbe naa lapapo, Uche Secondus pe mi pe ki lo de ti mo fe fi egbe naa sile, mo si
salaye pe mo ti so fun won pe mi o le wa pelu Bode George ninu egbe mo. Igba akoko ti alaga wa maa pe mi niyen. Gbogbo
igba ti mo wa ni atimole, ko seni kan bayii ninu won to ri temi ro, bee Bode
George gan-an ni idaamu ati isoro buruku ta a ni ninu egbe PDP l’Ekoo.”
O te siwaju ninu oro e
pe, gbogbo igba lawon omo eyin okunrin yii ti da ipade wa ru ni
Oregun atawon ibomi-in, ati pe ti awon ba foro ohun to won leti ni Abuja, nise ni won maa n so pe ka fi won sile, agba egbe ni
won, nnkan si n fojoojumo baje.
O ni, “Bakan naa ni oun
atawon eeyan e tun paro mo mi pe mo mo nipa isele to waye ni Eti-Osa, won lemi
ni mo pase pe ki won da wahala sile, bi ki i ba se opelope Olorun ati pe awon agbofinro sise won gege bii ise, won ko
so pe won ko ran mi lewon.”
Okunrin yii ti so pe lojo Aje, Monde
to n bo yii loun atawon eeyan e bii egberun meeedogun yoo sayeye ni papa isere
Agege niluu Eko lati fihan pe awon ti d’omo egbe oselu APC. Bee lawon eeyan e
naa lawon ti setan lati ba asaaju awon lo patapata. Nibe naa ni won ti so pe igbese awon yii
gan-an ni yoo mu opin deba egbe osleu PDP patapata l’Ekoo. Okan ninu won so pe,
“Bi awa bi egberun meeedogun ba fi PDP sile, meloo ni yoo wa ku
ninu egbe naa. Afaimo ko ma je pe PDP ti ku patapata nipinle Eko niyen.”
Sa o, Alagba Bode
George naa ti soro, okunrin oloselu yii ti so pe, aaye wa fun Salvador lati fi
egbe naa sile, niwon igba to je pe agbalagba to mo ohun to to si i ni okunrin
naa n se.
O ni, “Ki i se iru
asiko yii lo ye ko sare kuro ninu egbe wa, paapaa nigba ti iwadii si n lowo
lowo lori iku ojiji ti won fi pa Aborisade. To ba je pe awon kan ni
won n tan an wi pe ki o maa bo ninu egbe oselu APC, iro ni won jo n pa funra
won, nitori iyen ko ni ki iwadii to peye ma waye lori iku ti won fi pa eni
eleni.”
![]() |
Bode George |
Lasiko ti Bode George
se ifilole eto ikowojo loruko Oloogbe Adeniyi Aborisade nipinle Eko lo so oro
yii.
Ni
idahun si esi oro ti won fi kan an wi pe oun gan-an lo n da wahala sile ninu
egbe oselu PDP l’Ekoo lo ti so pe, “Salvador gan-an lo n dari egbe PDP l’Ekoo
bii pe ileese ara e lo sakoso e. Ohun ti a ba bo lati ile-ejo to ga julo, iyen
Supreme court; oun gan an ni ko tele e. Ohun ti ile ejo so ni pe, ki awon ti
won n tele Seneto Ahmed Markafi to jawe olubori ko ida marundinlaadorin (65%)
awon oloye ti won yoo maa sakoso nipinle kookan, ki awon ti Alli Modu Sheriff
ko ida marundinlogoji (35%). Salvador ko tele eleyii, nise lo n yan awon to ba
wu u sipo, ti gbogbo egbe n daru gudu. Emi ko ni mo le e ninu egbe, oun lo lo
funra e, awon ti won si n tan an wi pe ko maa bo, won ko le gba a, dajudaju,
idajo ododo gbodo waye lori eni to pa Niyi Aborisade.
0 Comments