GBAJUMO

IJA PARI: GOMINA OYO LOUN YOO BA YINKA AYEFELE KO ILEESE RADIO E PADA


Lode ariya nla kan ni Yinka Ayefele ati Gomina Abiola Ajimobi ti pade laipe yii, bo tile je pe wahala kan wa nile, nibe gan-an ni won ti yanju e, tawon eeyan si ri erin leeke awon mejeeji.
Olubadan ti ilu Ibadan, Oba Saliu Adetunji lo n sayeye aadorun-un (90) odun, nibe gan-an lawon mejeeji ti pade niluu Ibadan. Ojo yen gan-an ni gomina ipinle Oyo seleri wi pe oun setan lati tun ileese Yinka Ayefele ti won dawo laipe yii ko, ati pe isele ohun, o daju wi pe awon ota oun yoo fi gbogun ti oun gidi gan-an.
Laaro kutu Sannde to koja lohun-un ni ilu Ibadan mi titi, ileese redio FRESH FM to je ti Yinka Ayefele nijoba ipinle Oyo dawo, bi awon eeyan se n gbe awon to sise ohun sepe, bee ni won n ju epe nla nla fun Gomina Abiola Ajimobi. Sugbon ni bayii, gomina naa ti so pe oun setan lati tun un ko.

Egberin milionu naira (N800m) ni won so pe ileese redio ohun to, eyi ti won wo apa kan ninu e, ti won pe oruko e ni Music House.
Gbagi lawon eeyan ri i ti Gomina Abiola Ajimobi di mo Yinka Ayefele lori keke to jokoo to fi n rin si, nigba ti asiko ti to fun gomina lati soro lo fi i lokan bale wi pe oun setan lati ba a tun ko.
Ohun ti gomina yii so nibe lojo naa ni pe oun mo pe nise lawon ota oun ninu oselu yoo maa lo isele ohun lati fi ba ijoba oun loruko je, fun idi eyi, ohun yoo dojuti won, ileese naa yoo di kiko pada laipe yii.
Nibi ayeye aadorun-un ojoobi Olubadan, o fe ma si laami-laka oloselu nipinle Oyo ti ko ba won debe pelu awon oba alaye. Lara won ni, Rasheed Adewolu Ladoja, Oloye Christpoher Alao Akala, Abiola Ajimobi atiyawo e pelu awon gbaju-gbaja mi-in nile Yoruba.


Sa o, bi inu awon eeyan kan se n dun wi pe gomina ipinle Oyo ti so pe oun yoo ba Ayefele ko ileese e pada, bee lawon mi-in n beere pe se bee ni ijoba yoo ba awon mi-in toro kan naa ko tiwon pada, nitori ohun ti ijoba so tele ni pe, ki i se ileese Ayefele nikan lawon wo, ti Kola Daisi wa nibe, bee ni ti ileese Glo naa farako ninu isele ohun lagbegbe naa. Awon mi-in tie tun n so pe se owo Abiola Ajimobi lo fe fi ko o ni abi owo ijoba?
Gbogbo bo ba se n lo, la o maa fi to yin leti.  

Post a Comment

0 Comments