![]() |
Babatunde Olalere Gbadamosi |
Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP nipinlẹ Eko,
Babatunde Ọlalere Gbadamọsi tọpọ awon
eeyan tun mọ si BOG ti sọ pe ijọba
Baba sọ pe ti wọn n lo nipinlẹ Eko
ti su awọn araalu wọn si ti sun wọn kan ogiri, idi niyi ti won fi n wa ẹgbẹ oṣelu ti yoo jẹ ọna abayọ nibi ibo to n bọ lọdun 2019 ti
yoo le APC danu.
O sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade tawọn
oloye ẹgbẹ ADP
nilẹ Yoruba ṣe, eyi to waye niluu Eko. O sọ pe ijọba ti wọn n
lo lati nnkan bi ogun ọdun
sẹyin ti su awọn eeyan bayii, bo tilẹ jẹ pe o ti pẹ ti
wọn ti fẹ le wọn
danu, sibe ojooro ati awọn iṣẹ ibi tawọn to
wa nijọba naa n ṣe ni ko jẹ.
Gbadamọsi sọ pe lọdun 2003, ni wọn ti
kọkọ fẹ fi ibo le wọn
danu nigba ti ajo eleto idibo nigba naa ti kọkọ kede pe Funṣọ William lo wọle ṣugbọn nigba tilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, wọn ti ṣojooro pe awọn
lawọn wọle
pada ẹlẹẹkeji.
O ni, “Iyẹn tun lọ, lọdun 2007 tawọn
araalu tun mura silẹ lati jẹ ki Funṣọ William’s
wọle, ṣe lawọn ẹni ibi da ẹmi ẹ legbodo, awọn
eeyan wa sọ nigba naa pe awọn ko mọ ẹni to pa ọkunrin
naa ṣugbọn
idahun temi maa n fun wọn ni
pe awọn to jere nipa iku ẹ ni ki wọn ro
o si.”
O tun ṣalaye pe ipo to yẹ ki
ipinlẹ Eko wa kọ lo wa, bi a ba ni ka a sọ nipa eto ọrọ aje atawọn ise
idagbasoke. O fi kun oro e pe, nigba to jẹ pe
awẹn ẹbi kan ni wọn fẹ maa paṣẹ, ki
aṣẹ gbogbo ipinlẹ Eko wa lọwọ wọn, o
ni asiko ti wa to tawọn
araalu ṣetan lati fi ibo le wọn danu. Ko si nnkan to n jẹ babakresi tabi baba sọ pe mọ.
Oludije naa tun ṣalaye siwaju pe ẹgbẹ ADP nipinlẹ Eko ti n mura silẹ fun
yiyan awọn oludije ti wọn yoo dije labẹ ẹgbẹ ohun, o ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn yoo ṣe
ojuṣe wọn
lati dibo fẹni to ba wu won, ati pe ẹgbẹ naa ko setan lati fowo ra ibo lọwọ enikeni, ise rere to ni ni yoo gbe wole
lojo ibo.
O ni bi awọn ọmọ ipinlẹ Eko
ba le fun ẹgbẹ oṣelu ADP laaye lati jawe olubori ninu ibo gomina to n bọ naa, gbogbo nnkan tawọn fẹ ṣe lati le jẹ ki
ipinlẹ ọhun ba awọn
agbaye yooku mu lawon yoo se. O fi kun un pe, ko ni i gba awọn ju ọdun
kan lọ lati mu ayipada nla ba Eko, nitori awọn ti
ko to o lagbaye, o nibi ti wọ de bayii.”
Gbadamọsi so pe, “Awọn iṣoro ti ko yẹ ko
maa dojukọ wa bii omi, ina, atunṣe oju popo lawọn
araalu n dojukọ pẹlu bi owo ṣe n
wọle, bakan naa ni eto ibanisọrọ wa gan-an ko ja geere to, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ”
O wa beere pe iru ijọba wo wa ni a n lo nipinlẹ Eko. Ọpọ awọn to
n ṣakoso ipinlẹ Eko lo sọ pe
o yẹ ki wọn wa nibi ti wọn ti
n tọju won, ṣugbọn ni bayii, opin ti de ba iru awọn aṣaaju bẹẹ nitori wọn ti
sun awọn araalu kan ogiri.”
BOG ti so pe ohun ti awọn eeyan n wa ni ijọba
tuntun ti yoo le ṣe
gbogbo nnkan ti wọn ba n fẹ, ti ko ni si pe wọn fi
ara ni araalu.
O wa sọ pẹlu
idaniloju pe ireti ṣi wa
fun ẹgbẹ oṣelu ADP lati gba akoso ipinlẹ Eko, nitori ariwo ayipada rere ti ki i ṣe ti APC lawọn
araalu pariwo bayii.
0 Comments