Lati le fopin si awuyewuye to
gba ilu kan lori bi ijoba ipinle Oyo se da ileese redio, Yinka Ayefele wo ni
kutukutu owuro ojo oni, ijoba ipinle Oyo ti soro, ohun to si so ni pe, igbese
ohun waye lati le daabobo araalu ni.
![]() |
Yinka Ayefele ree |
Ninu iforowanilenuwo ti ileese
telifisan TVC, l’Ekoo se fun oluranlowo gomina ipinle ohun lori oro iroyin,
Ogbeni Tunji Bolaji lo ti salaye bayii pe, “Igbese ti ijoba ipinle Oyo gbe fun anafaani
araalu ni, nitori ipese aabo to peye fun dukia ati emi awon eeyan lo je ijoba
yii logun. Lodun to koja lojo kerinla osu kefa ni won koko ko leta si ileese
redio Fresh FM wi pe ibi ti won wa yen ko bojumu to, ohun ti ileese ijoba to n
ri si aato ilu so ni pe ki won sun seyin die, nitori titi marose to koja niwaju
ileese naa, emi awon eeyan le maa bo nibe lopo igba ti won ba gbe iru ileese
bee sibe. Eni kan to pe oruko ara e ni Aderonke Bamiduro lo gba iwe naa lowo
won. Nigba to tun di ojo kerinlelogun osu kejo, odun 2017 won tun mu mi-in lo
fun won nibe, Adebisi Akinfunmi lo gba a lowo won. Pelu awon iwe ti won ko si
won yii, ko si ohun kan bayii ti won se, leyin odun kan gbako nijoba too gbe
igbese. Ijoba Oyo ko ni ohunkohun lokan laburu si Yinka Ayefele, aabo dukia ati
emi awon eeyan lo je wa logun, idi ti won fi kolu ileese redio yen loni-in
niyen.”
![]() |
Oluranlowo ijoba, Tunji Bolaji |
Okunrin amugbalegbee fun gomina
Oyo yii tun fi kun oro e pe, “Nibi ti Ayefele n lo fun ileese Redio yen, kii se
iru nnkan to ye ki won maa se nibe niyen, ofiisi lasan nibe yen wa fun, ki i se
ibi to ye ki awon ero ti maa wo lo, wo bo, o lewu pupo fun emi awon eeyan ati
dukia, paapaa bi ibe tun se je agbegbe titi marose. Ariwo lasan lokunrin olorin
yen n pa, ko sigba kan bayii ti ile-ejo da wa lowo ko wi pe ki a maa se gbe
igbese lori wiwo ileese redio naa. Ohun ta a gbo ni pe Tusde ojo Isegun to koja
ni won sese gba kootu lo, bee ni ijokoo kankan ko ti i waye lori oro ohun, ti
yoo ba waye, boya lola Monde ni won sese maa jokoo lori e. Fun idi eyi, ariwo
lasan ni won n pa kiri, bee ki i se gbogbo ileese redio ohun
nijoba wo, Music
House lasan nikan ni won fowo ba, ise si n lo, awon eeyan si n gbo ileese Fresh
FM lori afefe. Igbese tijoba gbe, fun idaabobo emi awon eeyan ati dukia ni, awa
ko ni wahala kankan pelu Ayefele.”
![]() |
Ileeese Redio Fresh FM |
0 Comments