Bi odun ileya awon Musulumi se
n sunmo, ti kuku-keke a fe ra eran odun gbode kan, Ileese YEFADOT Food Company ti ko opolopo
eran agbo wolu, eyi to setan lati ta lowo pooku bayii.
Agbo nla kan pelu iresi ati
ororo ni ileese ohun so pe oun setan lati maa ta fun araalu ni egberun lona
aadota naira (N50,000)
Ninu alaye ti Aare Ileese naa
se fun Magasinni yii, Alhaja Yetunde Babajide lo ti so pe, “A gbe eto yii kale
lati mu aye rorun fun awon araalu ni, paapaa awon Musulumi ti won fe pa eran ninu
odun ileya. Eran to ni alaafia, to si je ojulowo ni ileese YEFADOT n ta. Bee la
se e ni edinwo lona ti ko fi ni i ni awon eeyan lara rara. Gege bi e se mo
akitiyan wa lori igbelaruge ise agbe ati ipese ohun amayederun fun araalu, eyi
gan-an ni koko ohun to mu wa gbe eto yii kale. Lara awon anfaani ti a fe fun
awon eeyan wa ni pe, bi won ba se n ra eran agbo yii, bee ni won yoo maa gba
Ororo, ti won yoo tun gba iresi pelu. Ko tan sibe o, eto ti wa nile lori bi won
yoo se ba won gbe eran yen denu ona ile won. Gbogbo eyi, a se e lati mu irorun
ba awon eeyan wa ni, nitori obe ko gbodo sele, bee la fe ki inu awon eeyan maa
dun lotun-un ati losi.”
0 Comments