GBAJUMO

O TUN N LO O! WON NI LONDON TI BUHARI N SA LO YII, AKOBA NI YOO JE F'EGBE OSELU APC

Buhari ree, London ti n pe baba

Fraide ojo Eti ola yii ni won ti kede e bayii wi pe Aare Mohammed Buhari yoo tun lo soke okun lati lo fun ara nisinmi.
Lasiko ti oluranlowo Aare orile-ede yii lori eto iroyin, Ogbeni Femi Adesina n ba awon oniroyin soro niluu Abuja lo fidi oro ohun mule. O ni, isinimi ojo mewaa ni Aare Muhammed Buhari n lo fun loke okun, ati pe Aare ti ko leta ranse si ile igbimo asofin agba nibi ti Seneto Bukola Saraki ti n solori won ati ile igbimo asoju-sofin lodo awon Yakubu Dogara lati fi to won leti.
Femi Adesina salaye pe, “Ni ibamu pelu abala marun-un-din-laadojo (145) nomba kin-in-ni (1), iwe ofin orile-ede yii, Aare ti gbe igbese to ye lati fi to awon ile igbimo asofin mejeeji leti. Ni bayii, ti Aare ti n lo si London, Igbakeji Aare orile-ede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo ni yoo maa dele de e, ti ohun gbogbo yoo si maa lo leseese.
Bo tile je pe isinmi ranpe ni Aare Buahri so pe oun fe lo fun niluu London, sibe ohun tawon kan n so ni pe ki i se iru asiko yii lo ye ki baba naa fi ilu yii sile, paapaa lori bi awon eekan nla-nla se n binu ya kuro ninu egbe naa bayii.
Awon ti won modi oselu daadaa so pe, asiko yii gan-an lo ye ki Buhari lo ipo e fi ba awon eeyan e soro ki won fiye denu, ki egbe naa tun le jawe olubori leekan si i ninu idibo to n bo lodun 2019. Won ni, ki i seru asiko yii lo ye ki baba naa lo jokoo sinu otutu niluu London, pelu ero wi pe, awon to ya lo yen ko le diwo ki oun ma tun wole leekan si i.
Baba agbalagba eni ogota odun kan to ba Magasinni yii soro salaye pe, “Irufe idaamu yii naa lo ba egbe oselu PDP nigba ti eto idibo 2015 n sunmo etile. Ohun tawon Jonathan naa lero nigba yen ni pe, mewaa ko le sele, sugbon nigba ti nnkan ti a n wi yii de, ogun sele, ogbon si sele pelu. Asiko yii lo ye ki Buhari atawon agbaagba ninu egbe naa wa atunto si oro egbe yii ti awon omo egbe n yo lokookan bii owo. Bi won ba lero pe ko ni i leyin lodun 2019, mo fe fi gbogbo enu so o wi pe, yoo ya won lenu gidigidi.”


Saraki ree to n fawon APC se yeye
bo se sawo inu egbe PDP lo

Te o ba gbagbe, lojo kansoso laipe yii nile igbimo asofin agba ni Dino Melaye atawon asofin akegbe e merinla mi-in binu ya kuro ninu egbe oselu APC lo sinu egbe oselu PDP. Ariwo tiwon yii naa ko ti i role, tawon akegbe won mi-in nile asoju-sofin naa tun ya repete lo sinu egbe oselu PDP.
Boro ohun se n lo ree lati nnkan bi ose meji, bawon gomina se n kuro ninu egbe oselu APC, bee lawon asofin n lo, eyi ti ko ye Seneto Bukola Saraki ati gomina ipinle re, Abdul-Fatah Ahmed sile. Pabanbari isele yii ni bi awon asofin bii metalelogun nipinle Kwara se ya kuro ninu egbe ohun leekansoso lo sinu PDP, bee gege ni Gomina Aminu Tambuwal ni Sokoto naa ti binu ko egbe ohun sile, ti Gomina Benue naa atawon asofin kan nipinle ohun si ba gomina won lo sinu egbe oselu PDP ti gbogbo won ti deye si tele lodun 2015.
Eyi gan-an lo mu awon eeyan maa so pe egbe oselu PDP ti di iyawo tuntun bayii, gbogbo oloselu patapata lo fe maa ba won se lasiko yii.
Sa o, awon kan ti so pe, o see se ki wahala mi-in naa tun be sile ninu egbe ti won n salo yii, paapaa to ba di asiko ti won yoo fa eni ti yoo dupo aare sile. Won ni eleyii gan-an lo si n fi awon Oshiomhole atawon Buhari lokan bale wi pe, awon ti won lo yen, ere osupa ni won se lo sibe, ati pe rederede to maa n gbeyin ere ohun, ni yoo gbeyim ibasepo won, nigba ti asiko ba to lati fa eni ti yoo dupo aare sile.

Post a Comment

0 Comments