GBAJUMO

ODUN ILEYA: JAMA’ATUL IZALATUL FEBUN T'ORE FAWON OMO ALAINIYAA


Ajo kan to n ri si oro awon omo ti ko niyaa ti won wa labe Jama’atul Izalatul sabewo sile awon omo ti ko niya to wa ni Babusalam, GRA, Ikeja fun ti ayeye odun ileya nibi ti won ti febun tore fawon to wa nibe lati le je ki inu tawon naa dun lasiko ayeye ohun.
Awon ebun bii aso, bata, fila atawon nnkan mi-in lorisirisi ni won fi tore fawon omo bi aadota. Won lawon se eyi ki awon eeyan naa le mo pe ara kan naa ni won, ati pe awon tun se e lati ran won lowo pelu ileri pe loorekoore lawon yoo maa yoju si won.
Ninu oro Mallam Hassan Idris to je olori awon omo ti ko niyaa naa, o dupe lowo ijo Jama’atul Izalatul fun iranlowo ti won se, bee lo tun ke si awon eleyinju aanu lorile-ede yii lati tubo maa dide iranlowo fawon to ku die kaato lawujo.

O ni nnkan pataki to je awon logun ju fawon omo naa ni eto eko ati idanilekoo loorekoore. O lawon ti fun opo awon omo to wa labe won yii lanfaani iru awon nnkan bee lati ileewe alakoobere titi de Yunifasiti.


Post a Comment

0 Comments