GBAJUMO

SHAARE NIPINLE KWARA MI TITI LOJO TI ILEESE OLOPAA JU LEKAN ALABI SILE

Lekan Alabi

Idunnu nla lo subu layo fawon eeyan Shaare nijoba ibile Ifelodun lasiko odun Ileya nigba ti omo won, Ogbeni Lekan Alabi, oluranlowo fun gomina ipinle ohun wonu ilu naa wa leyin to ti wa latimole olopaa lati nnkan bi osu meji seyin.
Fraide, ojo Eti to koja lawon olopaa so okunrin oloselu yii sile, leyin ti oun funra e ti pe oga olopaa patapata lorile-ede yii lejo lori bi won se ko lati ju u sile, leyin ti ile-ejo giga nipinle Kwara ti ni ki won si ju u sile na.
Ogbonjo osu karun-un odun yii ni won mu un si atimole lori esun wi pe o lowo ninu idigunjale to waye niluu Ofa, nibi ti opo emi ti sofo, ti won si tun pa awon olopaa naa.
Lekan ree ninu moto to gbe e wolu Shaare
Ahamo won yii ni Ogbeni Lekan wa titi di ojo kin-in-ni osu kejo odun yii nigba ti Adajo ile-ejo giga kan nipinle Kwara, Onidajo A.I. Yusuf  pase pe ki won gba beeli re, ati pe bi awon olopaa si se mu un sile lodo won yen, adajo agba naa so pe ko bojumu rara. Ogun milionu ati eeyan meji ti won lami-laaka laarin ilu ni won ni ki won duro gege bi oniduro fun un, eyi ti Lekan Alabi atawon agbejoro e ti sare wa lojuese.
Bo tile je pe won ti gbe igbese to ye lori ohun ti ile-ejo ni ki won ko sile yii, sibe nise ni ileese olopaa ko lati tu u sile, eyi gan-an lo mu un pe oga olopaa patapata lorile-ede yii, Ogbeni Idris Ibrahim lejo, esun ti won si fi kan an ni pe nise lo tapa si idajo ile-ejo, eyi to see se ki o fewon jura. Agbejoro Lekan Alabi, iyen Amofin Adebayo Adelodun (SAN) lo gbe igbese ohun, ese ofin kan ti won n pe ni Form 49 ni won lo, eyi ti won le fi ran oga olopaa lewon lori pe o ko lati tu Lekan sile, gege bi ile-ejo giga se pase. Ni kete ti igbese yii ti waye lawon eeyan ti n woye wi pe o see se ki won tu okunrin ohun sile, ki o wa ba awon molebi e sodun ileya, nigba to si di ojo Jimoh to koja ni finrinfirin ti gbalu kan pe won ti so o sile.
Lowo osan ojo Satide, ojo Abameta ni Lekan Alabi yo siluu Shaare, moto ayokele Toyota Camry alawo ewe lo gbe e wa, bee ni won gbe e yi gbogbo ilu ohun ka, ti o si n dupe lowo awon eeyan fun aduroti won.


Post a Comment

0 Comments