Gbajumo sorosoro nni, Niyi Ajetomobi ti kuro ninu egbe oselu
PDM bayii, o si ti ba egbe oselu APC lo patapata.
Okan lara awon oloselu toun naa kede wi pe oun fe dije dupo
gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu PDM ni okunrin olorin yii n se, sugbon
bo ti ku dede ki idibo ohun waye lo ko egbe ohun sile, to si ba egbe oselu APC
lo.
Lara igbaradi e lasiko to fi ife han wi pe oun fe dije dupo
gomina lo gbe ipolongo e lo sawon orile-ede wonyi Amerika, ilu London, Dubai ,
South Africa, Ivory Coast, Canada, Australia atawon ibomi-in lorisirisi ti awon
omo ipinle Osun wa.
Ojo kejila osu kesan-an odun yii lokunrin naa darapo mo egbe
oselu APC pelu awon ololufe e ti won jo wa ninu egbe PDM. Ilu Ilesa lo ti
darapo mo egbe ohun nibi akojopo-ita gbangba ti egbe oselu naa se. Tilu-tifon
ni gomina ipinle ohun, Rauf Aregbesola ati igbakeji e fi ki oun atawon alatileyin
e kaabo sinu egbe naa
Ninu oro Aladamo Ijesaa lo ti so pe, “Ife awon eeyan ilu mo
lo mu mi darapo mo oselu, nibi ipago Ojise Olorun, E.A Adeboye ni soosi Redeem
ni imisi yen ti wa si mi lara, ohun to si se pataki fun mi ni bi n o se mu igbe
aye irorun ba awon eeyan mi, ti ise agbe yoo je ojulowo, ti agbe yoo da bii
oba, ti awon ohun alumoni wa nipinle Osun yoo di ohun amusoro gidi.”
Siwaju si i, bi eto idibo ti se ku si dede ni gbajumo olorin
adamo Ijesa yii ti gbe rekoodu tuntun kan jade to pe akole e ni Igba Otun. Yato
si eyi, o je ojulowo sorosoro to maa n seto lori awon redio lorisirisi kaakiri
ile Yoruba, lara won ni Faaji FM, AJR Radio atawon ibomi-in kaakiri.
0 Comments