![]() |
Aare gbogbogboo fun PAN, Alhaji Fatai Yusuf |
Fun ilosiwaju orile-ede yii
nipa lilo ojulowo egboogi ibile lati fi toju aisan, egbe onisegun ibile ti won
n je Phytotherapists Association of Nigeria (PAN) ti ke si gbogbo ojogbon ti
won nimo nla yii lati wa foruko sile, ki won si darapo mo won.
Ninu ikede ti gomina egbe naa
nipinle Kwara, Alhaji Abdul-Rauf Quris fi sita lo ti ni ki awon eeyan ti Olorun fun lebun
lilo ewe ati egbo jade lopo yanturu wa darapo mo egbe naa to ti fidikale bayii si
ipinle Kwara labe Aare gbogbogboo f’egbe naa, Alhaji Fatai Yusuf Oko-Oloyun.
Ninu atejade ohun ni egbe yii
ti so pe, o se pataki ki awon to ni imo nla ti won fi n se awon eeyan loore yii
nipinle Kwara naa wa darapo mo egbe PAN, eyi ti yoo tubo gbe ise won laruge, ti
ijoba paapaa yoo ri won gege bi ojulowo dokita isegun ibile to se fokantan lori
oro ilera ni Nigeria.
Bakan naa legbe yii tun fidi e
mule pe orisirisi anfaani nla ni ojulowo omo egbe to ba ti foruko sile yoo maa
ri gba.
Won ni, “Orisirisi awon anfaani
ti ko legbe leni to je ojulowo omo egbe yoo maa ri. Lara e ni bi egbe PAN yoo
se ri i daju pe won gbase-gbonte lowo ijoba lori gbogbo egboogi to ba n ti
ileese won jade. Bakan naa ni egbe wa tun setan lati maa se iranlowo lori bi e
o se maa ta oogun yin lai si wahala kankan. Egbe to lami-laaka kaakiri agbaye
ni. Ohun ti a wa fun ni lati mu irorun ba gbogbo onimo to n lo ewe ati egbo
fi sewosan nla fun omo araye. Foomu ti wa nile egbe wa niluu Ilorin lagbegbe Odo-Ota
leyin ile-eja, ibe gan-an ni ofiisi wa n’Ilorin.
0 Comments