![]() |
Aare ile America, Donald Trump |
Bi ile America se n palemo eto
idibo to maa waye ninu osu kokanla odun yii, Aare orile-ede naa, Donald Trump
ti kilo fun orile-ede China ki won ma da soro oselu ile America, ti won ko ba
fe kan idin ninu iyo.
Nibi akojopo nla ti ajo agbaye
(UN) se loni-in ojo Wesde yii ni Trump ti soro yii, bee lo fi kun un pe, “Ohun
to fa ijangbon ti awon China n fa lese yii ni bi ijoba mi se gbena ko won loju
lori eto oro aje. Ko si Aare kan to ba won fa a ri, emi leni akoko. Iyen gan-an
ni won se n se kurukere kiri, ti won fe je ki emi ati egbe oselu mi fidi remi ninu ibo to maa waye. Won ko fe je ki a jawe olubori ninu ibo to n bo ninu osu kokanla odun
2018 yii.
“Mo fe fi asiko yii ki won
nilo, ki won ma se da soro oselu ile Amerika, ki kaluku lo koju mo orile-ede e,
ki won fi wa sile pelu oro orile-ede wa. Nipa oro aje ti mo ba won so sokoto
kan naa nitori e, fun ilosiwaju ile Amerika ni, fun idi eyi, ki won yaa tete so
gbeje mowo.”
Nibi ipejo nla ohun, awon asoju
ile China naa wa nibe, bee lawon naa n gbo esun ti Aare ile Amreika yii fi kan
won.
Sa
o, minisita fun oro ile okeere, Wang Yi ti so pe ko si ooto kankan ninu oro ti
Trump so yii nitori pe ko si ninu iwa ile China lati maa da soro oselu
orile-ede mi-in. O
ni, “A tako ohun ti aare ile Amerika so nipa orile-ede wa, awa ki i se bee, ati
pe ko si ninu ise wa lati maa da si oro ti ko ba kan wa. Iro patapata gbaa ni Aare Trump n pa mo ile China.”
0 Comments