GBAJUMO

E WO FIDIO TI WASIU AYINDE SE FUN GOMINA: WON LO SEE SE KO KO WAHALA BA A

Wasiu Ayinde olorin a ko mu-jo-jo niyi

Pelu bi nnkan se n lo yii, afaimo ki gbajumo olorin fuji nni, Alhaji Wasiu Ayinde ma ko ara e si wahala repete pelu fidio to se lati fi tabuku gomina lori wahala tiyen n koju lowo.
Bi fidio yii ti gba igboro kan lawon kan ti n so pe, ohun ti okunrin olorin yii se ti poju, nitori pe oro awon oloselu ko ri beenm won le pada yanju e laarin ara won, ati pe to ba sele bee, nibo gan-an ni Oluaye awon onifuji fe foju si.
Bawon eeyan se n so o niyen ni nnkan bi ojo meloo kan seyin, sugbon ni bayii, o jo pe gomina naa ti fe bo ninu wahala oselu to de ba a. Ohun ta a gbo ni pe igbese orisirisi ti n waye bayii laarin awon alenu-loro ninu egbe oselu APC ki okunrin naa le pada sile ijoba lodun 2019.
Ohun ta a gbo ni pe, ipolongo ita gbangba ti awon omo egbe oselu APC lo se laipe yii nipinle Osun, nibe gan-an loro e ti je jade, ti won si ti n wa ojutuu si bi yoo se bo ninu jogodi to wa, ti yoo si lo saa kan si i nile ijoba.
Bi iroyin yii ti gba igboro kan wi pe won yoo foriji gomina naa ti okunrin oloselu mi-in ti won n pariwo e kiri wi pe oun ni yoo ropo e lodun 2019 yoo si lo jokoo die naa lawon eeyen ti n bira won pe, ti oro naa ba yanju, ti Gomina ohun tun lanfaani lati pada sile ijoba leekan si i, nibo ni Alaaji Wasiu Ayinde to n pe gomina yii loruko orisirisi yoo foju si.
Te o ba gbagbe, ni nnkan bi ojo meloo kan seyin lawon fidio kan gba igboro kan, nibi ti gbajumo onifuji nni, Alaaji Wasiu Ayinde ti n ba awon kan soro lagbo faaji, to ni laye Tinubu, gbogbo wa la gbadun, bee lo tun se ri laye Fashola, sugbon were to wa nibe lasiko yii, nise lo maa senu dududu, epe la fi le e lo, ko le pada mo… were tibi, odun meta aabo lo fi ja mi lole, nigba ti mo n sise fun un ko sowo lowo were, sugbon ni bayii o ti rowo ji ninu ijoba, o wa sora e d'Olorun...a ti le e....a ti f'oro le e...a ti f'oro le were...epe aye, a ti fepe aye pa a...epe aye la fi pa a..."
Bee lokunrin yii tun se fidio kan to n korin pe e gba a lowo e, ko mo on lo…eni to ju ni lo, o le ju ni nu…”
Esun ti okunrin olorin yii fi kan gomina ohun ni pe lati bi odun meta aabo lo ti je oun lowo ti ko san an, iyen gan an lo fa a to fi n bu u, to tun n pe e loruko orisirisi.
Ni bayii, ti oro gomina yii ti n yanju pelu awon agbaagba egbe ti won lawon ko ni i satileyin fun un tele, ohun kan tawon eeyan n beere bayii ni pe, ti gomina ba pada, ti awon oloselu dari ji ara won, kin ni Wasiu Ayinde tun fe ko lorin?
Okan lara awon omo egbe oselu APC to ba wa soro salaye bayii pe, “Fidio ti Alaaaji Wasiu Ayinde fi sita yen, o ku die kaato gan-an ni o, se e mo pe oro awon oloselu ko se da si. Ohun to n sele si gomina yen lowo, iru e ti waye ri, ti won si yanju e laarin ara won. Ota ayeraye kan bayii ko si laarin awon oloselu, eni ti won pe lota loni-in, o le di amugbalegbee won lola. Okunrin olorin yii ko ba ti jokoo ti orin e jeje, sebi Olorun ke e, oro oselu to n da si kiri yii, afaimo ko ma bona mi-in yo fun un.”
Sa o, nibi ti oro gomina ti Wasiu Ayinde lawon ti fi epe lpa yii yoo yori si kaluku naa ni yoo foju ri.  

Post a Comment

0 Comments