GBAJUMO

‘IBO PAMARI: GOMINA AMBODE NI YOO JAWE OLUBORI’

Bo tile je pe iseju-iseju lawon omo egbe oselu APC l’Ekoo fi n ya kuro leyin gomina won, Akinwunmi Ambode, sibe ajo to n polongo fun un ti so pe okunrin naa ni yoo jawe olubori.
Nibi ipade kan ti awon ololufe e, ti oruko won n je Ambode Support Group pe loni-in ni Ogbeni Akeem Sulaimon, eni ti se oga agba fun ipolongo gomina naa ti ro awon omo egbe oselu APC lati jade lopo yanturu wa dibo won fun gomina naa ninu eto idibo pamari ti yoo waye lojo Monde, otunla yii.
Akeem Sulaimon ti ro awon omo egbe oselu naa lati sa akitiyan won ki Ambode le feyin Babajide Sanwo-Olu gbole, ki gomina naa tun le lanfaani lati sejoba Eko leekan si i.
Elomi-in to tun soro nibe lojo naa ni Ogbeni Kehinde Bamigbetan, eni ti se kominsanna fun eto iroyin, ohun kan ti oun naa so ni pe ki awon omo egbe oselu ohun dibo won fun Ambode, ki ise rere to ni fun ipinle Eko le te siwaju.
Sa o, o fe jo pe bi eto idibo pamari egbe oselu APC se n sunmo etile, bee lawon omo egbe oselu ohun n ya tele Babajide Sanwo-olu. Ni bayii, ninu asofin ogoji ti won wa nile igbimo asofin Eko, merinlelogbon ninu won bayii ti so pe Babajide-Sanwo-Olu lawon yoo tele. Bakana naa lawon alatileyin Muiz Banire, okan lara awon oguna gbongbo oloselu lagbegbe Mushin, l’Ekoo ti so pe ti Babajide Sanwo-Olu lawon naa setan lati se bayii.
Te o ba gbagbe, loni-in yii kan naa ni Ogbeni Obafemi Hamzat so pe oun ti jawo ninu erongba oun lati dije dupo gomina Eko, ati pe Babajide Sanwo-olu gan-an loun fe sise fun bayii, ki okunrin naa le fidi Gomina Ambode janle nibi ibo pamari ti yoo waye.
Pelu bi oro se ri yii, ohun tawon eeyan n so ni pe, yoo soro fun Gomina Ambode lati jawe olubori ninu ibo alabode, iyen pamari tawon omo egbe oselu yii fe se.
Ohun tawon eeyan kan wa n so ni pe, pelu boro se ri yii, o see se ki egbe oselu mi-in gba okunrin gomina yii mora, ti egbe oselu e ba ko o, ti won lawon ko fe ko lo leekan si i.

Post a Comment

0 Comments