GBAJUMO

IBO PAMARI L’EKOO: WON NI, BOYA NI WON KO NI I DOJUTI GOMINA YII LOLA

Ambode ree, won ni afaimo ki won ma dojuti i lola

Bi awon omo egbe oselu All Progressives Congress (APC) tipinle Eko se n gbaradi lati seto pamari egbe won lola, lati fi yan eni ti yoo dije dupo gomina lodun 2019, okan lara awon oludije, Hamzat Obafemi ti juwo sile fun Babajide Sanwo-Olu.
Nibi ipade oniroyin ti okunrin oloselu ohun pe loni-in ojo Abameta Satide lo ti fidi e mule. Ni kete ti igbese e yii waye lawon eeyan tin gbe e kiri wi pe, afaimo ki Gomina Akinwunmi Ambode ma ba itiju bo nibi ibo ko-mese-ko-yo ohun, eyi ti yoo waye ni ola Sannde, ojo Aiku.

Alaye ti Obafemi Hamzat se fawon oniroyin ni wi pe, oun gbe igbese naa latari ife ti oun ni si egbe, ati pe yoo wu oun ki gbogbo awon alatileyin oun gbarukuti Babajide Sanwo-Olu ko ba le jawe olubori ninu idije ti yoo waye naa.
Ni bayii, ti Hamzat Obafemi ti juwo sile fun Babajide-Sanwo-olu, laarin awon meji yii; Akinwunmi Ambode ati Babajide-Sanwo-olu ni idije ohun yoo ti waye bayii.
Te o ba gbagbe, ni kete ti anfaani ti si sile fawon oludije lati gba foomu orisirisi ipo ti won ba fe lo fun ni Ogbeni Akinwunmi Ambode ti gba foomu lati fi ife han wi pe oun tun fe pada sori ipo ohun leekan si i. Bo ti gba foomu yii naa ni okunrin kan ti oun naa ti sise daadaa pelu Asiwaju Bola Tinubu lasiko to je gomina Eko ati igbakeji e naa, Femi Pedro so pe oun naa fe dije dupo ohun, Babajide Sanwo-Olu loruko e. Latigba yen si ni ariwo e ti gba igboro kan, ti orisirisi ese ti won so pe Akinwunmi Ambode se awon baba isale oloselu l’Ekoo ti bere si je jade.
Hamzat ree nibi to ti fa owo Jide Sanwo-Olu soke
Yato si Babajide ati Ambode ti won fe dije loruko egbe oselu APC l’Ekoo bee ni Hamzat Obafemi naa. Yato si asiko yii, igba akoko ko ree ti okunrin naa yoo jade wi pe oun fe di gomina, o ti koko jade ri nigba ti Babatunde Fashola n pari saa keji re, oun ati okunrin oloselu kan ti won pe ni Sasore ni paapaa, sugbon nise ni won fidi remi nigba yen, ti Akinwunmi to je omoloju fun Oba Eko, Oba Rilwan Akiolu, bee lo tun je ayanfe fun Asiwaju Bola Tinubu nigba yen si gbegba oroke.
Ni bayii ti nnkan ti daru mo gomina Eko lowo, to je pe gbogbo awon alaga ijoba ibile ni won ti duro gbon-in leyin Babajide Sanwo-Olu, ti awon agba oje nidii oselu l’Ekoo paapaa so pe awon ko fe e mo, Babajide lawon fe ba lo, won ti ni ibo pamari ola yen, nnkan ko le senuure fun gomina yii.
Yato si eyi, Iyaloja General, iyen Oloye Folashade Ojo, eni ti se omo Asiwaju Bola Tinubu naa ti fowo si wi pe Babajide Sanwo-Olu lawon ati gbogbo oloja pata n ba a lo, nibe yen gan an lawon eeyan ti n so pe, afaimo ko ma je pe itiju ni Ambode yoo ba bo nibi ibo pamari ti egbe naa fe se lola.
Ju gbogbo e lo, pelu bi oro se ri yii, nibi ti oro Ambode ati Jide Sanwo-Olu yoo yori si lola, gbogbo e pata la o maa fi to yin leti.  

Post a Comment

0 Comments