GBAJUMO

IDAAMU OLUSEGUN MIMIKO: EGBE AWON OSISE NI KO LE DIJE DUPO AARE LORUKO EGBE OSELU AWON *WON NI ALAIMOORE NI

Olusegun Mimiko

L’ojobo Tosde oni ni gomina ipinle Ondo tele bo si gbangba lati kede wi pe oun naa setan lati dije dupo aare orile-ede yii, sugbon bo ti n so oro ohun lawon egbe osise, iyen Nigeria Labour Congress ko je ko tutu rara ti won fi so fun un pe, iru e ko lawon n wa, nitori o ti huwa aimoore segbe ohun nigba kan ri.
Nibi ipade awon oniroyin ni gomina ipinle Ondo tele, Olusegun Rahman Mimiko, eni tawon eeyan tun mo si Iroko ti kede erongba e lati dije dupo aare.
Okunrin kan to ti se alaga fun egbe awon osise ni Nigeria ri, Abdulkadir Abdulsalam naa wa nikale lojo naa, won loun gan-an lo fowo si i pe ki  Olusegun Mimiko jade lati dije dupo aare loruko egbe oselu Labour Party lodun 2019.
Bi iroyin ohun ti gba igboro kan ni Ogbeni Ayuba Wabba, eni ti se aare egbe awon osise (NLC) ati Arabinrin Ebere Ifendu, iyen alukoro fun egbe naa ti sare pe ipade awon oniroyin, ohun ti won si so ni pe, awada buruku lokunrin omo Ondo yii n se, nitori awon ko ni i gba iru e laaye lati fi owo tabi ola to ni da opo egbe awon ru.
Ninu oro Wabba, iyen alaga egbe osise lo ti so pe, “O se pataki ki a je ki gbogbo aye mo wi pe egbe awa osise ko fowo si ipo aare ti Olusegun Mimiko loun fe lo fun loruko egbe oselu wa, Labour Party lodun 2019. Ko see se fun okunrin omo Ondo yii rara, nitori pe Mimiko ko ni ohun kankan se pelu egbe wa. Egbe oselu gidi ti o fese rinle daadaa ni, ti apapo egbe osise NLC ati Trade Union Congress pelu egbe awon iyaloja (Market Women Association) atawon omoleewe pawopo fi oruko e sile ni, bee la ni iwe eri iforuko sile wa, eyi to wa lowo akowe agba fun egbe wa. Fun idi eyi, ko si olowo-igbo kan to le fi owo ra wa niye, bee la ko ni i gba enikeni laaye lati da opo gidi ni a ni nle fun egbe yii ru.
Ayuba Wabba, Aare egbe osise
“Fun idi eyi, mo fe fi asiko yii ke si Mimiko ko tete rin siwaju, egbe yii ki i se egbe to le maa lo, ti a tun pada gbe ju sile, iru eyi to se nigba kan to fi depo gomina, ati pe A.A Salam to n tele kiri, won jo n tan ara won ni, oun ko ni alaga egbe yii, bee ko lenu kankan, ki won ye tan ara won je.”
Saaju asiko yii nigba ti Mimiko n ba awon oniroyin soro lo salaye idi pataki to fe fi gbapoti, o ni, “O se pataki ki a gba orile-ede yii sile lowo ise ati ebi. Opo omo orile-ede yii lemi won n sonu lojoojumo latari wi pe won fe kuro ni Nigeria lo soke okun. Gbogbo eyi la setan lati mojuto, bee la o fopin si ise ati ise to n ba awon omo Nigeria finra."  


Post a Comment

0 Comments