GBAJUMO

IYALODE OJODU, YETUNDE BABAJIDE FE SAYEYE OJOOBI L’EKOO *BEE LO TUN FE KO OPOLOPO EEYAN NISE OWO LOFEE

Monde, ojo Aje to n bo yii ni Iyalode Ojodu, Oloye Yetunde Babajide yoo sayeye ojoobi, bee leto ti wa lati ko egbelegbe egberun eeyan lorisirisi ise owo lofee.
Ninu iforowero ta a se pelu e lo ti fidi e mule wi pe, “Ona ara ni mo fe se ojoobi mi lodun yii. A fe ko opolopo eeyan nise owo lofe. Lawujo wa loni-in, o se pataki ki eeyan ni ise owo kan tabi ju bee lo ki ise ati osi ko le dinku lawujo wa.
“Nigba kan ti mo sayeye aadota odun, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma lo wa korin lojo naa, sugbon eyi ti mo fe se lasiko yii, ara oto ni, a fe fi ran opolopo eeyan lowo ni, a fe mu inu awon eeyan dun, a fe ko won nise owo, bee la setan lati ro won lagbara, ti awon naa a le da duro, ti ise ati ebi yoo le dinku patapata.”
Oloye Yetunde Babajide fi kun un pe, “Orisirisi anfaani ni yoo tun si sile lojo naa, nibi ti awon akosemose yoo ti wa nikale lati gba awon eeyan nimoran, ati iyanju lori bi ojo ola won yoo se dara.”
Gbongan GABOVIS Hall to wa ni Aina street, l’Ojodu Berger, l’Ekoo lo so pe eto pataki ohun yoo ti waye, ati pe aago mewaa aaro ni eto yoo bere lojo naa ti se ojo Aje, Monde to n bo yii.


Post a Comment

0 Comments