GBAJUMO

JIBITI OSELU NI GOMINA AMOSUN FE LO, EMI KO KURO LEKUN IDIBO MI RARA- OLUMIDE OSOBA

Olumide Osoba

Onarebu Olumide Ọṣọba ti pariwo sita pe gbogbo ọgbọn ti Gomina Ibikunle Amosun fẹ fi mu ori oun mọ abẹ lo ti ja sofo bayii, nitori ipo to foun si ninu ipinsipo lati ṣoju Abẹokuta South nile igbimo aṣoju ṣofin labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni ko tọna rara.
Ninu atẹjade kan ti ọkunrin naa fi sita lo ti sọ pe, ẹkun Abẹokuta North, Ọbafẹmi Owode ati Ọdẹda loun soju fun lọdun 2011 si 2015 nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, ati pe o je oun iyalenu bi Gomina Ibikunle Amosun se kọ orukọ oun sabẹ Abẹouta-South, nitori pe ko sigba kankan bayii toun ni in lọkan lati fawọn eeyan oun silẹ, bẹẹ loun si wa pẹlu wọn ni gbogbo igba.
O ni bawo lawọn ti wọn ko to irinwo yoo ṣe wa jokoo sibi kan ti won yoo so pe awọn poju eeyan ọgọfa miliọnu lo.
Olumide fi kun un pe nigba toun fẹ forukọ silẹ fun idibo, wọọdu kẹta ni Owode labẹ ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode loun ti forukọ silẹ, oun ko si figba kankan bawọn ṣe oṣelu ri ni Abẹokuta South ti Gomina ni koun ti jade bayii.
O ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba toun ri orukọ oun nibi toun ko ti bawọn ṣe oṣelu ri, ati pe ko sigba kankan toun bawọn jokoo papọ pin ipo, bẹẹ ni ko sẹni to jẹ koun gbọ.
Okunrin oloselu tii se omo gomina ipinle Ogun tele, iyen Olusegun Osoba ti yara ẹ sọtọ gedegbe lori orukọ ti wọn gbe jade naa.

Lori idije pamari eyi ti ẹgbẹ lapapọ fọwọ si fun ti ibo 2019, O ni oun ṣetan lati dije nilana ti wọn gbe kalẹ fun ẹkun Owode, Abẹokuta North Ọdẹda toun ti wa, oun ko bawọn si ninu ibo ọtẹ tawọn kan gbe kalẹ bayii.
Gbogbo awọn to ri orukọ ti wọn ni Amosun gbe sita naa ni wọn gba pe Gomina naa fẹ fi da wahala silẹ laarin awọn ẹyin Oloye Oluṣẹgun Ọsọba ni. Won ni o jo pe gomina naa ko mọ pe awọn yẹn naa gbọn ọgbọn oṣelu ju u lọ daadaa.
Ni bayii, a gbọ pe iran lawọn eeyan naa n wo gomina ti wọn si n reti ibi ti wọn yoo gba mu un, ti ẹru yoo ti ba a.

Post a Comment

0 Comments