GBAJUMO

JIGAN BABAOJA, GBAJUMO OSERE TIATA JEBUN MOTO NLA *KEKE MARWA LO GBE LO, TOYOTA TUNTUN LO GUN LO SILE



Idunnu nla lo subu  layo fun gbajumo osere tiata nni, Abimbola Kazeem, eni tawon eeyan tun mo si Jigan Baba Oja.
Nibi idije kan lokunrin onitiata yii lo, moto ayokele Toyota boginni lo je, ohun to si so ni pe, “Emi ni inu mi dun ju loni-in. Keke Marwa ni mo wo wa sibi loni-in, sugbon bi a ti se n soro yii, Toyota tuntun, ti idi enikeni ko kan ri ni mo n gun lo sile. Ohun idunnu nla lorisirisi ni Olorun ti se fun mi lodun yii, ohun kan ti mo si le so ni pe, mo dupe lowo Olorun oba”
Okan lara awon osere to maa n se awada daadaa ninu sinima ati fiimu agbelewo ni Kazeem Jigan Baba Oja, bee lo tun je olorin. Laipe yii lokoki e tubo gba igboro kan nigba to se ere awada oniseju bii meloo kan, to pe ni Se o mo age mi ni, to tumo si pe se o mo ojo ori mi. Ere ohun saaba maa n waye laarin eeyan meji nibi ti won yoo ti maa jiyan nipa ojo ori ara won.
Jigan Baba Oja ati Aremu Afolayan lo koko se e, Ori ero ayelujara kan ti won n pe ni Instagram lo gbe e si, bo se di pe awon eeyan gba a niyen, ti omode n se e, ti agbalagba naa n se e, paapaa laarin Femi Adebayo ati baba e, Oga Bello. Bi arifin lawon eeyan yoo pe e, sugbon awada lasan ni won fi se.
 Ju gbogbo e lo, Kazeem Jigan Baba Oja ti ni moto tuntun, o jo pe, odun 2018 yii, igbega nla nla lo n sele ninu aye okunrin naa.

Post a Comment

0 Comments