Lara awon osere tiata Yoruba ti won je laami-laka laarin ilu ni
Ogbeni Abdul-Wahab Adeshina, eni tawon eeyan tun mo si J.J.C niluu Abeokuta.
Kaakiri lokunrin osere omo ilu Shaare nijoba ibile Ifelodun
nipinle Kwara yii ti lo, ki o too fikale si ilu Abeokuta, nibi toun naa ti
daraba nla nidii ise sinima bayii.
Abdul-Wahab lo ni Morakinyo Films Production, eyi ni alaye to se
fun MAGASINNI ALORE nipa irin-ajo e nidii ise sinima. E maa ba wa ka lo…
BI MO SE BERE SINIMA
Oruko mi ni Abdul-wahab Adeshina Jimoh, eni tawon eeyan tun
mo si Omo Iya Igbaja. Oruko egbe osere mi ni Morakinyo Adeshina Films
Production. Oruko tawon eeyan tun mo egbe osere tiata mi si daadaa ni JJC.
Mo bere ise tiata yii lodun 1984, baba kan lo wa ni adugbo
wa, Baba Rafiu ni won n je, oun gan-an ni Olorun fi se sabaabi mi, oun lo maa n
sere ori-itage niluu abinibi mi, Shaare, to wa nijoba ibile Ifelodun nipinle
Kwara.
Mo woye wi pe ohun ti baba yen n se, emi naa le se e daadaa,
nitori pe lati kekere ni mo ti lebun ere ori-itage, mo mo ilu lilu daadaa, bee
ni mo tun mo orin ko pelu. Ni gbogbo igba yen ti mo wa nileewe, mo maa n korin,
bee ni mo le lu ilu daadaa. Bi mo se bere niyen .
BI ISE SINIMA SE GBE MI KURO NILUU MI
Ki emi naa le jeeyan nidii ise yii, iyen gan-an lo mu mi te
siwaju, ti mo kuro niluu mi. Lara awon ti won je oga mi nigba naa ni Yisa
Olorun-o-je, mo gbe odo e daadaa niluu Ilorin, bi odun meji ni mo lo nibe.
Leyin e ni mo tun gbe lodo Alhaji Ogun Majek n’Ibadan, odun kan aabo ni mo lo
nibe yen.
Nigba to tun ya mo lo si Eko lodo gbajugbaja elere ori-itage
lasiko yen, Obalende loruko e, igba yen lo n gbe ni Maskala ni Agbotikuyo
l’Ekoo.
Odun kan ni mo lo lodo e ki n too pada si ilu mi ni Shaare.
Bee ni mo tun bere tiata pada ni ile.
BI MO SE PADE IBRAHIM CHATTA
Nigba ti mo pada si ilu mi, lasiko ti mo n so yii, bii 1991
si 1992 ni, ohun ti mo kiyesi ni pe, gbogbo ere ti a n se nigba yen, bii ere
abule lasan ni mo kaa si, asiko igba yen naa ni Ibrahim Chatta wa darapo mo mi.
Ilu Bacitta lohun-un lati pade. Bi odun mefa lo lo lodo mi niluu Shaare. Nigba
to ya la so wi pe ki a kuku maa lo si Eko.
ISORO AKOKO TO FE YO ISE TIATA LOKAN MI
Eko yen la wa ti idaamu kan koko sele si wa, okan lara awon
omo ti mo n ko kiri, Muri loruko e, oun ati Abdul-Rasaq Salam Karohunwi ni won
jo jade lojo, ki Olorun ba mi forum ke e, ina lo da jo o, isele yen lo pa omo naa.
Ibrahim atawon omo ilu mi ti won gbo
nipa isele yen ni won gbiyanju pupo lori e, nitori omo yen lo bii ogoji ojo o
le die ni osibitu jenera l’Ekoo ki o too jade laye.
BI MO SE DERO ABEOKUTA
Wahala iku omo yen tun fe mu mi pada si Shaare, sugbon ki n
too gbe igbese yen, okan mi kan so fun mi pe ki n gbiyanju Abeokuta naa wo, o
see se ki Olorun se aamin si igbiyanju mi.
Nigba ti mo de si Abeokuta, odo omokunrin kan ni mo de si,
Kayode Akindina, o duro ti mi daadaa, nise lo gba mi towo-tese.
OHUN TI MO FI ROWO MU L’ABEOKUTA
Kayode Akindina yii lo n mu mi kaakiri, to n fi mi han awon
osere lorisirisi wi pe, eni yii ni ebun, e je ki a maa lo o ninu ere sinima wa.
Ohun to wa mu mi yato niluu Abeokuta nigba yen ni pe, emi
leni akoko to mo ijo jo daadaa laarin awon osere tiata. Ki n too de, ko si
onijo kankan ni gbogbo Abeokuta.
Ijo yen gan-an lo sare tan imole mi niluu ti mo sese de yii,
nise ni awon eeyan n so fun ara won kiri wi pe omokunrin kan ti wa, J.J.C loruko
e, onijo bii okoto ni.
Bi awon osere egbe mi se tewo gba mi niyen, bakan naa ni oga
wa, Olaiya Igwe naa tun mu mi mora, bi mo se deni to ri ibi de si niluu
Abeokuta niyen.
OORE NLA TI HAMED ALASAARI SE FUN MI
Eni akoko to koko lo mi ninu sinima e ni Oloogbe Isola
Durojaye, eni tawon eeyan tun mo si Alaasari. Fiimu kan to pe akole e ni Ile
Aye la se lodun naa lohun-un. Okan lara awon sinima to pokiki mi niyen, bo se
di pe awon eeyan bere si pe mi si sinima niyen.
AWON FIIMU TI MO TI SE
Mo dupe lowo Olorun nitori emi naa ti se awon sinima to
loruko daadaa, ni bayii, sinima ti mo ti se ti le ni mewaa. Lara e niwonyi: Eru Olorun, Eje orisa; ile oojo; Aja
Onibode; idajo okan; imule aje; eegun nileejosin; ojo isegun; Ta ni ade ori mi;
orisa ijaya.
SINIMA TO KO ORIIRE BA MI
Ojo
isegun ni sinima kan ti mo dupe pupo ju le lori, bo tile je pe
fiimu idajo okan gan-an lo mile
daadaa ninu gbogbo awon sinima, sibe Ojo
isegun yen, alubarika wo o, mo si dupe lowo Olorun lori e.
MO FE GBE ITAN ILU SHAARE JADE GEGE BI SINIMA
Ni bayii, mo ti bere ise lori sinima tuntun mi-in ti mo pe
akole e ni Isale Odo, bee la tun fe se sinima lori itan ilu abinibi mi, eyi ti
yoo mi ilu titi, Osoja ni akole
sinima ohun maa je. Ilu Shaare laarin awon ilu Igbomina, ilu nla kan ni to ni ojulowo itan gege bi omo Alade. Gege bi omobibi ilu ohun, a ti se opolopo iwadii, bee la ti sise takuntakun lati gbe itan ilu naa kale, eyi ti yoo je anfaani nla fun awon omo wa atawon ti won n bo leyin lati le fi mo nipa ibi ti a ti se wa, ohun to mu wa duro sibi ta a wa loni-in, atawon ohun isenbaye lorisirisi ti ilu yii ni, to ye ko di mimo fun gbogbo agbaye.
ISORO TA A TI KOJU
Orisirisi isoro lati koju nidii ise yii, sugbon loni-in, a
dupe wi pe araye ko fi bu wa, bee la ni igbagbo wi pe ola si maa dara ju oni
lo, nitori a ko fi Olorun sile, bee la o se ole pelu.
LOJO TI OMO MI GBA AMI EYE WALE
Awon omo mi naa n se daadaa lenu ise yii, paapaa eyi to je
abigbeyin mi. Abubakar Adeshina loruko e, o maa n kopa daadaa ninu awon sinima
ti a n gbe jade, kaakiri ni won ti maa n pe e si ise. Bakan naa ni omo mi, Olalekan
Teslim Adeshina naa, oun ti se ere ori-itage to gbami eye odomode to n se
daadaa nidii ise sinima ri. Yato si awon wonyi, bakan naa lawon omo mi meji mi-in naa tun n se daadaa nidii ise sinima, awon ni Basit ati Monsurat Adeshina, osere lawon mejeeji naa.
Ju gbogbo e lo, mo ni awon eka kaakiri ti won n je Morakinyo
Films Production. Mo ni okan ni Shaare ti se ilu mi, bee lo wa ni Abuja naa.
IPINNU EGBE MI
Ti a ba maa fi ri odun marun-un si i, egbe wa yoo ti tubo
gbooro si i, bee lanfaani yoo ti wa daadaa lati maa lo ya sinima wa loke okun
naa.
ISORO AWA OSERE TIATA
Ohun kan to n ko isoro ba wa ni oro awon to maa n se ayederu
ise wa, won ko je ki a rowo mu daadaa nidii ise yii, ki Olorun gba wa lowo won.
Owo iyebiye la fi n se sinima wa, bee lo maa n je ohun ibanuje bi awon eeyan se
maa n se ayederu e, ti won a tun maa pin kaakiri funra won, ki Olorun saanu wa
nidii ise yii ni.
OJO TI MI O LE GBAGBE
Ojo manigbagbe nidii ise yii ni ojo ti okan lara awon
omoleyin mi jona, Muritala loruko e, isele yen mu ise yii su mi patapata, ojo
ti inu mi baje ju niyen, omo ilu mi ni, oro ohun fee mu okan mi si kuro nidii
ise sinima.
Ojo manigbagbe mi, ti mo sunkun, bo tile je pe ekun ayo ni
mo n sun lojo naa, ni ojo ti omo mi gba ami eye, odomode to mo ere se ju ni
gbogbo ipinle Ogun. Obasanjo lo wa lori oye lasiko yen, eko ofe ni won fun un paapaa,
Teslim Olalekan Adeshina loruko e. Ibe ni mo ti ronu pe, ase mo le sise yii
debi ola. Mo sunkun nijo naa o, sugbon ekun ayo gbaa ni!
0 Comments