GBAJUMO

O TAN! IYIOLA OMISORE TI BA EGBE OSELU APC LO *WON LAWON YOO BA WA NNKAN NINU IJOBA TUNTUN

Awon omo egbe oselu APC ti won wa ba a sepde ree

Bi ajo INEC se n mura lati seto idibo lawon ijoba ibile merin lola nipinle Osun, Orolu, Ile-Ife ati Osogbo, Seneto Iyiola Omisore, ti ke si awon alatileyin e wi pe egbe oselu APC ni ki won dibo won fun.
Nibi ipade oniroyin to pe loni-in ni Iyiola Omisore, eni to dije labe asia egbe oselu SDP ti ke si awon alatileyin e ati gbogbo awon eeyan ijoba ibile mereerin ti atundi ibo yoo ti waye lati dibo won fun Isiaka Oyetola, eni to n dije loruko egbe oselu APC.
Ninu oro e lo ti so pe, “Awon agbaagba egbe oselu APC ti wa ba mi, leyin ti a jo jiroro, ti won si ti gba lati ba wa komo-lu=po=bo, ninu ijoba tuntun ti yoo waye l’Osun, awa naa setan lati sise pelu won. Won ti lawon fara mo eto egbe oselu wa, fun idi eyi, awon la n ba lo, mo ro gbogbo omo egbe oselu SDP atawon ololufe wa lati dibo won fun egbe oselu APC, a o jo sejoba ni, a ti ni adehun bayii.”
Te o ba gbagbe, niniu ibo to waye lojo Abameta Satide to koja, Seneto Iyiola Omisore lo se ipo keta, nigba ti Ademola Adeleke, omo egbe oselu PDP n le iwaju, ti Gboyega Oyetola si wa nipo keji, ki ajo INEC to kede wi pe atundi ibo gbodo waye loni-in Tosde, lawon ijoba ibile mererrin yii, ti konu-n-koho ti koko waye tele.  
Ninu ibo ohun ni Ademola Adeleke to siwaju ti ni ibo egberun lona igba-o-le-erinle-laaodota ati ibo mokandin-leedegbinrin (254,699), nigba ti  Isiaka Oyetola toun dije labe asia egbe oselu APC ni tie ni ibo egberun lona igba-o-le-erin-le-laaodota ati ibo oodunrun-o-le-marun-un-din-laadota (254,345).
Seneto Iyiola Omisore, to dije loruko egbe oselu SDP, to siketa ninu idije ohun pelu ibo egberun lona eji-din-ni-aadoje-o-le-mokandinlaadota (128,049).


Post a Comment

0 Comments