OHUN TAWON EEYAN KO MO NIPA MI
Oruko mi ni Alhaja Aminat
Babalola Balogun, eni ti gbogbo aye tun mo si Omotayebi, bee ni wo n tun mo mi si
Iya Kekere Eko, koda awon mi-in a tun maa pe mi ni Small Body, big engine, eyi
to tumo si pe, O kere loju, sugbon ohun
alumoni to n be lara e, olowo-iyebiye ni.
Mo dupe lowo Olorun lori ohun
gbogbo, odun yii gan-an lo pe odun merindinlogbon (26) ti emi naa ti n ba ise
orin bo wa. Lati kekere lawon obi mi ti faramo on, e ma je ko ya yin lenu o,
Kristeni ponbele gan-an ni iya mi, bee Musulumi daadaa ni baba mi pelu. Won
fowo si ise orin ti mo gbe dani yii, bee ipa won lori ki emi naa le lu aluyo,
ko se fowo ro seyin rara.
Bi mo se bere orin Islam, lati
ileekewu gan-an ni mo ti bere, saaju ki n too darapo mo won, eni kan wa to maa
n korin fun won nileekewu yen. Oruko ileekewu yen ni Daarul Taarif wal-Arabiyy
wal Islamiyy, Itire l’Ekoo lo wa.
Nibe gan-an ni mo le so pe, mo
ti bere. Emi n korin nigba yen gege bi ebun, mi o mo pe o le digi ola fun mi
gege bo se da loni-in.
Mo ranti pe ojoobi Anobi wa,
eyi ta a mo si Maolud Nabbiy la fe lo lasiko naa. Orisirisi ileekewu lo maa wa kopa
nibi idije ni gbagede nla lati fi sami ayeye ojoobi Asaaju wa yii, bee lawon eto
mi-in yoo tun wa lolokan-o-jokan. Lara e naa ni orin kiko naa maa wa. Se mo so
tele wi pe o leni to maa n saaju orin nileekewu yen ki emi too de. Oun lo ye ko
tun saaju, sugbon lasiko ti a n se igbaradi lowo, eni yen ko se e daadaa, inu
aafa wa ko dun si i, nni won ba na an lojo yen, loun naa ba da a sibinu. Nibe
naa lo ti so fun Aafaa wi pe, orin ko loun wa ko nileekewu, kewu loun wa ke.
Lojo ti mo n wi yii, idije ku
bii ojo meji, adugbo kan to n je Shitta ni papa isere kan ti won n pe ni Obele
ni Suurulere l’Ekoo la maa n lo. Oro ti mo n so yii ti pe gan-an ni o, oro yen
a fee to ogbon odun bayii.
Nigba ti oro si ti ri bayen,
lemi ba so fun Aafaa wi pe ki won je ki n bo sibe, mo le korin yen.
Bi mo se gba a niyen, bee ni
Aafaa naa tun ko mi lawon ohun to ye ki n wi, bi a se se e niyen o. Nigba ti a
debi idije, pelu ogo Olorun, awa la gbegba oroke. Bi irin-ajo yen se bere niyen
o. Ileekewu la ti bere ko too di pe a debi ta a de loni-in.
BI MO SE BERE SI SE REKOODU
Lati ileekweu yen naa la ti
bere si gbe rekoodu jade, ohun to fa sabaabi e ni pe, Aafa mi je eeyan kan to
ni akikanju daadaa; rekoodu mi akoko ta a gbe jade nigba yen la pe akole e ni Olorun ran mi lowo. Ileekewu yen naa ni
mo wa ti mo ti ko egbe jo, oruko ta a si fun egbe yen ni Taarif Singers.
Ko si ibi inawo ti won ki i pe
egbe wa si nigba yen, bee la n te siwaju ninu eko kewu wa, ti a si tun n korin
naa pelu. Asiko igba yen naa la se rekoodu akoko, ti mo pe ni Olorun ran mi
lowo. Ko pe sigba yen naa la tun se
elekeeji, ti mo pe ni F’ere si ise mi,
leyin naa ni mo se Allahu Afeezu.
Meta ni mo se nibe yen, nigba to ya la tun te siwaju lati se rekoodu fawon
mi-in, akole eyi ti mo se nibe yen ni Soro
Mi Dayo ati Maa soriire.
OMOTAYEBI TI WON
N PE MI…
Eni ti mo mu gege bi oga mi nidii
ise orin ni Ayeloyun, iyen Alhaji Qamardeen Yusuf Odunlami. Lasiko igba ti mo fe
kuro lodo won ni won fun mi ni oruko yen, Omo-ti-aye-loyun-bi, sugbon awon
eeyan ni won so o di Omotayebi latari lilo girama ede Yoruba, iyen isunki, nni
won ba n pe mi ni Omotayebi. Oga mi daadaa ni Ayeloyun n se, bee lo duro ti mi
daadaa.
Mo ti se opolopo rekoodu, lara
won ni Oja Ayo, Happy day naa wa
ninu e, The News naa wa, bee ni mo
se Ogbon die.
Leyin e ni mo se Oore Idunnu, Esan naa tele, Kadara naa wa ninu e. Gbogbo eyi ta a
ranti, a ti fe to meedogun ti mo se. Oja
Ayo gan-an lo so mi dolokiki. Ni nnkan bi odun metala seyin ni mo se e,
Rekoodu nla kan to so mi di olokiki niyen.
KO SI ARA TI EEYAN N DA LAYE TI MI O TI I FI
ORIN DA
Ohun idunnu loro mi pada ja si,
ti won ba so pe eeyan korin-o kole nidii e, mo dupe, ti won ba so pe eeyan fi n
ra ile, a dupe Olorun ko je ki won bi wa pe ki la ti ri gbe se. Bee ni mo ti fi
gun moto igbalode, bee la tun ti te siwaju lo sawon ile okeere. Mo si dupe lori
awon omo pelu wi pe Olorun ba wa se a ri owo fi to won.
Ko si ibi ti idaamu ko si, ki
Olorun ma da wa laamu. Opo igba ni mo maa n so wi pe ti eeyan ko ba ti i loruko,
opo igba ni inu eeyan a maa baje, to maa dabii pe eeyan ko mo ise se. Abi nigba
ti won ba n pokiki awon to ti ga legbee eeyan, ti e si jo n sise kan naa, inu
tohun ko ni i dun, sugbon ju gbogbo e lo, Olorun nikan lo ni deede, ati pe ti
asiko ko ba ti i to; nise ni sise-sise maa n da bii ole. Bee asiko kaluku ko ni
i tase. A dupe o, ki Olorun ma je ki a ri ibanuje. Ayo ni lojo gbogbo.
Awon omoota ni o, awon yen
gan-an fe le mu ise yii su mi. Nigba ti okiki yii de, won fe le mi nidii ise
yi, abi nigba ti won ba yabo eeyan ni kete ta a ba korin tan, bi eeyan ko ba si
fun won lowo, ijangbon nla ni. Sugbon pelu aduroti Olorun ati ife ojise nla re,
Anobi wa Muhammed, mimi kan bayii ko mi wa nidii ise ohun, ise Olorun ti a n je
n te siwaju si i lojoojumo.
IYATO TO WA NINU
ORIN ISLAM BAYII
Nigba ti awa bere ni nnkan bi
odun meedogbon o le seyin, iyato wa ninu e si ohun to gba ode kan bayii. Opo ni
ko fe mo wi pe orin esin ni awon n ko bayii. Bee lopolopo gan-an paapaa ni won
ko fe kose, lagbaja n korin, emi naa lohun orin ni won n ba kiri. Lagbaja ti di
irawo osere, emi naa gbodo nirawo lawon eeyan n se kiri bayii, bee okun ko le
gun-gun-gun ko ma ni ibi ti won ti fa a wa. Bi opo ko se fe kose mo, lo n da
opo nnkan ru.
AKOBA TO WA NINU REKOODU
ALASEPO (DUET)
Oro nipa rekoodu alasepo yen,
ki i se pe ko dara, sugbon ewu wa ninu e. Ohun to fa sabaabi e naa ni bi awon
eeyan ko se fe kose, to je pe nise ni won fe di gbajumo olorin lojiji. Bee ko
si irawo osere kankan ninu gbogbo wa, Olorun nikan ati ojise e ni won ni irawo.
Kani loooto ni a ba ni irawo ni,
ko ye ki elomi-in ni irawo loni-in, ko tun wa deni ti won ko ni i gbo oruko e
mo lola. Fun idi eyi, Olorun nikan lo ni irawo, ko si eda kan bayii to ni in.
Eni ti Olorun a fun ni okiki
latari rekoodu alasepo, iyen duet, o ti di dandan ko ni in, bee eni to maa ni
okiki latari eyi to ba se funra e, yoo kuku ni in. Iru emi bayii, rekoodu ti mo
se funra mi ni Olorun fi barika si fun mi.
Okiki yen bere latori Ojo Ayo,
to fi dori News titi dori Happy Day, Ogbon die, Oore idunnu ati Esan. Gbogbo awon
rekoodu yen, emi nikan ni mo se e.
Ohun to tun sele ni pe, akoba
nla ni kaseeti alasepo n ko ba awon eeyan wa, nitori eni to je pe Tayebi nikan
lo feran lati maa ra rekoodu e, to ba ti wa ri i ninu rekoodu alasepo, to si ra
a, se e mo pe a ti tun ra eyi to ba da se, o le ma rorun fun tohun. Ibeere ti
mo fe bi awon eeyan ni pe, se bi rekoodu ti a n da se funra wa nigba kan se n
ta lasiko yen lo se n ta nisinyi?
Bakan naa lo tun je pe, ti awon
oga wa ti won n ra rekoodu lowo wa ba ti ri alasepo ti irawo osere merin ba ti
wa ninu e, won le ma ra a ju egberun lona aadojo naira lo (N150,000). To ba wa
ri bee, elo ni eni to nise gan-an fe fun mi? Elo lo maa fun awon irawo osere meta
tabi merin mi-in ta a jo ba a se e?
Awon ti won sese n dide bo ni
oro yii ba wi ju, sugbon kinni kan ni mo mo, ti eeyan ba se rekoodu gidi, to ni
awon orin gidi ninu e, ko sigba ti eeyan ko ni i di gbajumo nla.
Nigba ti mo se rekoodu kefa
laye too mo pe mo n korin, loni-in a dupe. Emi o ni ki won fagile o, nitori
ninu aburu, daadaa tun maa n wa ninu e naa. Ohun to se pataki ni bi a se gbodo
fi odinwo si i.
Ohun to tie tun buru ni pe,
ninu awon ti won n gbe jade yen gan-an, omi-in ki i ni itumo gidi. Bee lo tun
ye ki a maa mura daadaa, ti a ba n ba awon okunrin sise papo, ka fi laakaye si i.
Opo eeyan lo n wo wa, a si gbodo se bii olorin Islam.
Bakan naa ni mo tun fe ro ijoba
ki won ni ajo ti a maa ye orin Musulumi naa wo ki a too gbe e jade, o ye ki gbedeke le wa lori ise wa, ti aseju
ko ni i wo o.
Rekoodu alasepo ni ona to gba
wulo, akoko, o je ki orin Islam tubo di gbajumo nla laarin awon orin yooku,
sugbon kiko opo irawo olorin jo lati fi se rekoodu kan, ko mu ilosiwaju ba wa
o, ti a ba fi oju oro aje wo o daadaa.
OJO IWAJU ORIN
ISLAM DARA
O ni awon ohun ti a gbodo tele
ti a ba fe ki orin Islam ni ilosiwaju gidi. A gbodo so orin ti a n ko, o gbodo
ba esin wa mu, irin ese wa naa gbodo ba esin wa mu, isesi wa naa se pataki, ki
a si je arikose rere gege bi musulumi, ki o si maa han ninu ise wa ati isesi
wa.
Ojo ola wa dara, bee la n rawo
ebe si Olorun lojoojumo, ko tubo mu ileri re se ninu aye wa. Won ti mo wa
daadaa lorile-ede yii, Ki Olorun tubo ran wa lowo, ki a le gbe orin yii kaakiri
agbaye, ki Islam ti a si fi n saponle e yii gbe wa kale. Ki Olorun ma je ki a
kanju ku, ki o ma se wa ni eni ti ko ni i dola, to lo n da osu mejila. Ki
Olorun ko tubo saanu fun wa.
0 Comments