GBAJUMO

WASIU AYINDE TI SALAYE IDI TO FI PE GOMINA NI WERE

Oluaye Fuji, Wasiu Ayinde

Nibere ose yii ni fidio ohun gba igboro kan, bii orisi meta ni paapaa, Alhaji Wasiu Ayinde, Oluaye fuji loun atawon ore e jo n se faaji nibi kan, nigba ti faaji si wo o lara daadaa tan, lo da yeye gomina ohun sile, bo ti n pe e ni were lo tun n bu u lawon eebu mi-in pelu.
Bo tile je pe Wasiu Ayinde ko daruko gomina to n ba wi gan-an, sibe ko seni ti ko mo pe wahala to de ba gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode lo fa fidio ti Oluaye ya. Se ohun to sele si gomina; ni bi awon agbaagba egbe, paapaa awon ti won sunmo Bola Tinubu se so pe awon ko ni i satileyin fun un ninu ibo odun 2019, eyi gan-an lo ko wahala ba gomina, ti Oluaye naa si raaye so ohun to wa ninu e si i.
Bi fidio yii ti gba igboro kan lawon eeyan ti n fehonu won han lori e, paapaa okan lara awon onifuji bii tie, Alhaji Abass Akande Obesere, bee lawon mi-in naa soro, ti kaluku si n so pe, ko ye ki Oluaye fuji tun maa dakun wahala to de ba gomina naa, ati pe o see se ki oro ohun yanju, to ba si yanju nibo gan-an ni Aranbanbi omo Ojusagbola yoo foju si.
Latigba ti fidio yen ti wa nigboro, ko seeyan kan bayii to le so pe oun gbo kinni kan lenu Oluaye, sugbon ni bayii, atejade kan ti wa nita bayii, oruko eni to ko o si ni Olasunkanmi Marshal, iyen oruko Alhaji Wasiu Ayinde.
Ninu atejade ohun ni Oluaye ti so pe, “Mo dupe lowo eyin omo Nigeria, paapaa lori ohun to sele ni nnkan bi ojo meloo kan seyin, ninu eyi ti opolopo awuyewuye ti n lo kaakiri. O se pataki ki emi naa so bi oro se je, bo tile je pe pupo ninu awon to je ore atawon alabase ni oro ohun le ma han si daadaa, paapaa lori ohun to mu mi se ohun ti mo se.
Oluaye and Ambode
“Ki i se pe mo n gbiyanju lati salaye boya ohun ti mo se yii letoo tabi ku die kaato nibi, dipo bee alaye ti mo fe se ni pe, mo je okan pataki ninu awon omo orile-ede yii to ni ipa to n ko nipa iloswiaju e ati bi awon nnkan se n lo, paapaa gege bi ojulowo omo egbe oselu pataki kan.”
Wasiu Ayinde fi kun oro e pe, “Gege bi awon eeyan se maa n so wi pe ko seeyan kan bayii ti ko ni eje oselu lara, irufe e lemi naa, nitori eeyan eleran ara ni mi. Fun idi, mo fe ro awon eeyan wa ki won fi laakaye won ba emi naa dogba lori oro to wa nile yii, ki won sinmi eebu ati enu egan, paapaa ebi orisirisi ti won n da mi lori igbese ti mo gbe lori oro to wa nile ohun.
“Ipa mi ninu oselu koja ajosepo to le maa waye laarin olorin atawon oloselu ti won ba n gbe ise fun un, dipo bee, ojulowo omo egbe oselu ni mi, ti enu mi si tole daadaa ninu egbe. Oju ti mo fe ki awon eeyan fi wo oro ohun niyen. Oro mi koja olorin to n korin fun egbe oselu nikan, omo egbe ni mi, bee emi naa lenu daadaa. Igbese ti mo gbe, ohun ti mo lero wi pe o le mu ilosiwaju rere ba awujo wa ni.” Bi atejade ohun se lo niyen.
Ni tododo, o fe ma si ibi ti egbe oselu APC ti lo se ipolongo won kaakiri Nigeria ti Alhaji Wasiu Ayinde ko ni i ba won debe. Ohun kan ti awon eeyan si n gbe e kiri nigba kan ni pe, oun paapaa fe gbe apoti ibo loruko egbe awon Tinubu niluu e ni Ijebu.
Te o ba gbagbe, lara awon oro to wa ninu fidio to se lo lo bayii,  “Laye Tinubu, gbogbo wa la gbadun, bee lo tun se ri laye Fashola, sugbon were to wa nibe lasiko yii, nise lo maa senu dududu, epe la fi le e lo, ko le pada mo… were tibi, odun meta aabo lo fi ja mi lole, nigba ti mo n sise fun un ko sowo lowo were, sugbon ni bayii o ti rowo ji ninu ijoba, o wa sora e d'Olorun...a ti le e....a ti f'oro le e...a ti f'oro le were...epe aye, a ti fepe aye pa a...epe aye la fi pa a..."
Sa o, ohun kan tawon eeyan si n tenumo naa ni pe, were atawon oruko abuku mi-in to pe gomina ohun ko ye lenu iru oloruko nla ti oun gan-an n se laarin ilu.

Post a Comment

0 Comments