Alaga egbe oselu APC, Adams Oshiomhole
ti kede wi pe ibo pamari to fe waye nipinle Eko ati Imo ko ni i le waye mo
lola.
Ojo Aje Monde, lojo ti
orile-ede yii yoo sayeye ominira ni won sun eto idibo ohun si.
Te o ba gbagbe, nipinle Eko,
lojo naa lawon omo egbe oselu APC yoo dibo yan enikan laarin Akinwunmi Ambode
ati Babajide Sanwo-olu gege bi eni ti yoo gbe Asia egbe oselu ohun fi dije-dupo
lodun 2019 ninu idibo gbogboogbo.
Awon eeyan ipinle Imo naa, iyen
awon omo egbe oselu APC naa yoo seto tiwon lojo Aje Monde ohun bakan naa.
0 Comments