Lati se koriya fun Aare ileese
YEFADOT Group of Companies, Oloye Yetunde Babajide, ileese Sunlight City
Foundation ti fun un lawoodu ami eyi eni to n sise takuntakun lori riro araalu
lagbara.
.Ninu oro ti awon alase ileese
Sunlight so lasiko ti won gbe awoodu naa fun Iyalode Ojodu ni won sapeju
obinrin naa gege bi ogunna gbongbo kan ti ileese e n mu ilosiwaju nla ba awon
eeyan lawujo, paapaa awon mekunnu, atawon ko-la-ko-sagbe latari awon eto
ekose-owo atawon ohun amayederun mi-in ti ileese YEFADOT fi n ro awon araaalu
lagbara.
Won ni latari igbese yii, opolopo
eeyan ni won ti dolokoowo, ti won si n se daadaa, ti ise ati osi si ti dohun
igbagbe ninu aye won.
Won ni eyi gan-an lo sokunfa awoodu Empowerment
Fellowship eyi ti won fun obinrin naa laipe yii.
Ninu alaye Yetunde Babajide, eni to tun
je asaaju awon obinrin ninu egbe oselu APC, ti won n sepolongo fun Aare Buhari lori
bi yoo se tun pada sejoba leekan si i, o ni, ami eye pataki yii fi han wi pe,
ise ti a n se laarin ilu, awon eeyan n kiyesi i. Koriya ni eleyii je, bee la o
tubo te siwaju, nitori ohun to je ileese YEFADOT logun ni bi osi ati ise yoo se
dohun igbagbe lawujo wa, paapaa lasiko ijoba Muhammed Buhari yii.”
Yetunde Babajide te siwaju ninu oro
e pe, “Anfaani nla wa daadaa ninu ijoba to wa nita yii, ijoba mekunnu gan-an lo
wa nigboro bayii, bee ohun ti ko sele ri nipa riro mekunnu lagbara lona ti won
yoo fi maa rije-rimu; nijoba yii ni lokan fun kaluku.
Nitori e la se n pe eyin eeyan wi pe
ki e maa bo lodo tiwa, ki a le fi ona orisirisi han yin lori bi eyin naa se le
da duro pelu ise owo kan gboogi, ti a o si tun duro wamuwamu ti yin lori bi
nnkan ti e ko yii yoo se wulo fun yin, ti e o si ri owo fi se e daadaa.”
Babajide ti wa dupe lowo ileese
Sunlight City Foundation, bee lo seleri wi pe, ileese oun ko ni i kaare okan
lati ri i pe awon mekunnu bo lowo isen ati osi lawujo wa.
O ni, “Opolopo ekose owo lo wa
nileese YEFADOT, bi a se lawon ti won n kose agbe, bee lanfaani wa fawon eeyan
lati kose ose sise, buredi oloyin, gaari yiyan, atawon nnkan mi-in
lolokan-o-jokan to le dowo kiakia.
Nibi ti aye de bayii, o se pataki ki
eeyan kose owo kun ohun yoowu to ba n se, eyi gan-an la wa mu ni okunkundun
nileese wa, a si dupe wi pe a n te siwaju ninu e lojoojumo, ti iyato si n de ba
awujo wa pelu.”
0 Comments