GBAJUMO

AWON EEYAN AMBODE PARIWO, WON NI OJORO LAWON BABA ISALE APC FE SE FUN GOMINA OHUN LOLA


Bi egbe oselu APC se n mura lati seto idibo pamari e lola ode oni, Tusde ojo keji, Ogbeni Daud Olasheu, eni ti se igbakeji alaga egbe naa nijoba ibile Somolu ti so pe, ojooro lawon agbaagba egbe ohun fe se fun Gomina Ambode.
Awon alatileyin Gomina Ambode, ti won sewode yii ti so pe, awon ko nigbagbo ninu eto idibo ti egbe naa fe se, nitori pe pupo ninu awon omo egbe oselu ohun ti won fe dibo won fun gomina naa ni won ko ni kaadi idanimo egbe ohun lowo. 
O le ni igba eeyan ti won sewode naa, ti won gbe akole orisirisi dani, ati ewe lati fehonu won. Daud Olasheu, to ko won sodi ti so pe, aimoye omo egbe oselu APC ti won setan lati dibo won fun Gomina Ambode ni won ko fun ni kaadi idanimo egbe.  
O ni, "Won se eyi ki Babajde Sanwo-Olu le m'oke ni, bee gbogbo eeyan Eko lo mo pe ise takuntakun ni Ambode se nipo gomina.
Sa o, Lola Tusde, ojo keji osu kewaa odun yii ni egbe oselu All Progressive Congress, egbe onigbale ti so pe oun yoo seto idije pamari ohun, eyi ti yoo waye laarin Gomina Akinwunmi Ambode ati Babajide Sanwo-Olu.
Nibi ipade oniroyin ti alaga egbe naa nipinle Eko, Ogbeni Tunde Balogun pe loni-in ojo Aje yii lo fidi oro ohun mule.
Okunrin oloselu yii ti so pe kaadi idanimo, to fi awon omo egbe oselu ohun han gege bi omo egbe ni won yoo lo lola. Bakan naa lo so pe, “Kaadi yii lawon eeyan yoo fi wole si gbagede ti eto idibo ohun yoo ti waye. Leyin ti won ba wole tan, ti iforuko sile ati ayewo finnifinni ba ti waye, la o bere eto idibo lati fi yan eni ti yoo gbe asia egbe yii lati dije dupo gomina loruko egbe oselu wa lodun 2019.
“Gege bi e se mo, idibo yii yoo waye laarin eeyan meji pere ni, Gomina Akinwunmi Ambode ati Ogbeni Babajide Sanwo-Olu.”
O te siwaju pe, ibo naa ko ni i nilo apoti idibo kankan, nise lawon omo egbe yoo to siwaju posita, iyen aworan eni ti won ba fe tele, ti awon eleto yoo si ka won leyo kookan lati fi moye eeyan to dibo fun oludije kan pato.
O ni, “Bi a o se se e niyen, a ko nilo iwe pelebe kankan ti a o te ika si, bee ni apoti eyo kan bayii ko ni i wulo lola. Eeyan la maa ka, a ko ni i ka iwe idibo, eni ti ibo e ba si ti po ju naa legbe yoo fa kale laarin Akinwunmi Ambode ati Babajide Sanwo-Olu.”
Bi egbe oselu APC se so o ree, ti ohun gbogbo ba si lo bo ti ye, ola yii kan naa ni awon eeyan yoo mo eni ti egbe oselu APC yoo fa kale.
Te o ba gbagbe, lati nnkan bi ose meloo kan seyin ni awuyewuye lorisirisi ti gba igboro Eko kan lori eni ti yoo dije loruko egbe oselu APC loddun 2019. Ola yii ni yoo je igba keta ti won yoo sun idibo ohun si.
Bi wahala ohun si se bere ree, ni kete ti gomina Eko, Akinwunmi Ambode ti gba foomu lati dije dupo ohun leekan si i, bee naa ni okunrin kan ti won n pe ni Babajide Sanwo-olu naa gba a. Bayii ni ariwo bere, ti awon oloselu nla nla n to leyin Babajide Sanwo-olu, ti orisirisi esun nipa Gomina Ambode si bere si yoju sita gbangba. Oro kan ti awon omo egbe oselu ohun si tenumo ni pe, okunrin naa ko ni i pada wa mo, a n bo, a ti de ti won so lodun 2015 yen, iru ede yen, awon ko tun ni i so o nipa Akinwunmi Ambode lodun 2019.
Nibi toro de duro niyen o, Gomina Ambode ti so pe oun setan lati dije pamari pelu Sanwo-Olu, bo tile je pe won ni won ti pe gomina yii si koro wi pe ko jawo, ki awon ba a wa nnkan mi-in ninu ijoba.
Bee ni Jide Sanwo-Olu atawon to n ti i leyin naa so pe, o ti di dandan kawon feyin Ambode janle, ki oun si lo asia egbe naa fi dije lodun to n bo.
Ninu jogodi oro yii naa ni Ambode ti pe ipade oniroyin, nibi to ti pe Jide Sanwo-Olu ni odaran ti ko le wo ile Amerika mo. Bo tile je pe ko daruko e, sibe awon eeyan mo wi pe okunrin naa lo n ba wi. Bee lo tun so pe alawoku ni, ati pe osibitu ti won ti toju e, kaadi idanimo e si wa nibe daadaa.
Sanwo-Olu naa ti soro, o ti ni awawi asan ni Ambode n se, ati pe itiju nla lo je nigba ti oun wo bi okunrin naa ti se n soro lori telifisan, nitori yoo soro fenikeni lati gbagbo pe iru awon oro bee le maa jade lenu odidi gomina.
Boro won se wa ree, bee lopo eeyan ti so pe, leyin ibo pamari yii, nibi toro ohun yoo ja si, gbogbo aye pata ni yoo ri i.

Post a Comment

0 Comments