GBAJUMO

BABA IJESA ONITIATA DASOJU ILEESE BOOKU CHICKEN *OJULOWO ADIE NI WON N TA NIBE


Gbajugbaja osere ori-itage alawada nni, Olanrewaju Omiyinka, eni tawon eeyan tun mo si Baba Ijesa ti di asoju ileese to n ta eran adie lopo yanturu bayii, won lawon fe ko fi tie ran awon lowo ni.
Ileese BOOKU Chicken, eyi ti irawo e gba igboro kan bayii latari adie gidi ti won n ta fun araalu ni Baba Ijesa n soju fun.
Ileese Agro-Park Foods and Spices Limited lo ni Booku Foods, lara ohun ti ileese naa n se ni ipese ounje gidi fun tita fun araalu. Lati fa oju awon alabaara won mora, paapaa lori bi eto okoowo ti won sese tun dagbale yii se je otun, eyi gan-an lo mu won yan Baba Ijesa, iyen gbajumo alawada laayo lati je asoju ileese naa, ti yoo si lo ipo e ati okiki nla to ni lati fi mu ilosiwaju ba okoowo adie ohun.
Yato is ileese to n ta Booku Chicken, awon ileese mi-in to lami-laaka ti Baba Ijesa n se asoju fun ni ileese to n pon oti Trophy beer ati ileese kan to maa n ba awon eeyan kole, to tun maa n ba won ta a tabi ra a.

Lose to koja ni Baba Ijesa towo bowe lati je asoju fun ileese naa, ninu eyi ti awon ti won je oga agba nileese Agro Park Foods and Spices Limited ti wa nikale, bee ni Ogbeni Dayo Badmus, eni ti  se oludari eto iroyin atawon ohun to ba je mo ibasepo Baba Ijesa ati awujo naa wa nibe pelu.
Ninu oro alakooso eto iroyin fun Baba Ijesa lo ti so pe, “Ajosepo to ni itumo gidi lo maa waye laarin Baba Ijesa ati ileese to n se Booku Chicken yii. Akoko ninu e ni pe, ojulowo adie ni Booku Chicken ti ko ni amulumala kankan ninu n ta fun araalu, bee ojulowo alawada ponbele ni Baba Ijesa, ti a ba n so nipa awon ti won di opo sinima mu lorile-ede yii. Eyi  fi han wi pe, ise nla ni ileese Booku Chicken naa se, ti won fi sawari eni to kun oju osunwon gan-an, iyen Lanre Omiyinka.”

Ninu oro awon alase ileese naa ni won ti fidi e mule wi pe, adie ti awon n ta yato si ohun ti awon eeyan ti le maa ri tele. Won ni, “Adie to n ti ileese tiwa jade, ojulowo ounje gidi ti ko ni kemika ninu won n je, bee ohun ti a kojopo ti a n fun won gege bi ounje, orisirisi nnkan asaralooore bii ewebe atawon egboogi mi-in la lo papo, eyi gan-an lo mu won yato si ohun tawon eeyan ti n ri tele.”
Siwaju si i, oga agba nileese ohun, Adetoro Olayomi ti salaye lajori ohun to mu won yan Baba Ijesa gege bi asoju ileese naa, alaye to se ni pe gege bi Booku Chicken se je ohun jije tawon eeyan n fe kaakiri, o ni bee gan-an ni awada Baba Ijesa naa se ri ninu sinima, to je pe ti ko ba ti i si ninu sinima, a je pe iru sinima bee ko ti i ni oyin ati adun to ye ko wa nibe ni.
“Gbajumo osere nla kan ni Baba Ijesa, to je pe ko si irufe awon eeyan ti ki i feran re ninu sinima, yala eeyan je alakowe, tabi eni ti ko ka rara, nise ni awada e maa n mu ogbon dani, ti ko si seni ti ki i fe teti si i.”  
O ni bee gan-an ni oro “Booku Chicken se ri o, nitori ko si eya, ede tabi elesin kan ti ko le je e, nitori ojulowo ounje to maa n sara looore ni adie Booku Chicken n se, bee ni ko won rara, talika n ra a, bee lawon alowolodu naa n ko o lopo yanturu.”

Adetoro ti fi da awon alabaara won loju wi pe ko sigba ti won n fe adie yii ti won ko ni i ri i ra ni gbogbo awon ibi ti awon ti n ta a. O ni, adie to le ni egberun lona igba (200,000) lo ti wa nile bayii, ti alaafia to peye wa lara won, ti owo won ko tun ga ni lara rara. Bakan naa lo so pe, ohun tawon eeyan mo ileese na mo ni, ounje aladidiun, to ni alaafia ninu, ti ki i ni eeyan lara lati ra.






Post a Comment

0 Comments