GBAJUMO

‘IBA GANI ADAMS N FE IRANLOWO AWON GOMINA ILE YORUBA’


Ki ilosiwaju alailegbe le ba ile Yoruba ati Nigeria lapapo, Iba Gani Adams, ti ro awon gomina lati wa ojutuu si gbogbo ona to ti baje, ki ijanba moto le dinku, ki igbe irorun si le wa fun kaluku.
Aare Ona Kakanfo ile Yoruba soro yii nibi ayeye igbade odun mewaa lori ipo ti Zaki Arigidi Akoko, Oba Yisa Olanipekun se laipe yii.  
O ni, ti awon ojuna wa ba dara nile Yoruba, anfaani nla ni yoo je fawon oyinbo atawon mi-in ti won fe wa da ileese nla nla sile, ti ise ati osi yoo si dinku daada nile Yoruba ati Nigeria lapapo.
Iba ninu oro e fi kun un pe, ti ileese ba wa lopo yanturu, araalu yoo ri ise se, ti ara yoo tu gbogbo ilu daradara, ati pe, ti ojuna ba dara, ijanba moto yoo dinku, ti ibanuje, ekun ati aso yoo dinku laarin ilu.
Siwaju si i, Iba Gani Adams so pe, ohun ti oun sakiyesi ni pe, ojuna to lo si ilu Arigidi ko daa rara,  bee lawon ona to wa ninu ilu naa ko se e gba rara. O ni, anfaani nla ni yoo je ti ijoba ipinle Ondo ba le satunse si opo ojuna nipinle naa, ki ilosiwaju le ba awon eeyan ibe, paapaa eto oro aje, nitori ti oju popo ba dara, awon to fe da ileese sile yoo wa, agbe naa yoo ri ere oko gbe wa sigboro, ti ipinle Ondo yoo si ru gogo si i ninu kata-kara.
Oba Olanipekun ninu oro tie ti ro awon eeyan ilu e lati tubo fowosowopo pelu ori ade, ki ilosiwaju le tubo ba ilu naa. 

Post a Comment

0 Comments