Gomina ipinle Eko, Ogbeni
Akinwunmi Ambode ti so pe, oun setan lati sise fun eni to jawe olubori ninu ibo
pamari to waye lana-an ki egbe oselu APC le jawe olubori l’Ekoo lodun 2019.
Ninu ikede ti gomina ohun se
losan-an oni lo fidi oro ohun mule. O ni, “Mo dupe lowo egbe oselu APC to fun mi
lanfaani lati se gomina ipinle Eko lati nnkan bi odun meta aabo seyin ta a ti
wa nile ijoba. Mo dupe aduroti ti eyin araalu fun wa, bee ni mo fe fi asiko yii
ki Ogbeni Babajide Sanwo-Olu ku orirrie.
“Mo setan lati sise papo pelu e
ki egbe wa le jawe olubori ninu ibo to n bo lodun 2019.”
Gomina yii tun dupe lowo
Asiwaju Bola Tinubu atawon agba egbe ohun fun aduroti won. Bakan naa lo ti
seleri wi pe gbogbo ohun ti oludije-dupo gomina, iyen Babajide Sanwo-olu ba
nilo lati mo ni oun setan lati la ye e yekeyeke, ki irorun le wa fun un.
Te o ba gbagbe, kaakiri ipinle
Eko ni eto idibo pamari ti waye lana-an laarin Gomina Akinwunmi Ambode ati Babajide
Sanwo-olu. Sanwo-olu lo jawe olubori nigba ti gomina yii ni tie fidi remi.
0 Comments