Soosi kan ti oruko e nje Liberty Ministry ni Obawole lagbegbe
Iju, l’Ekoo lawon olorin emi nla meta yii, Dare Melody. Bunmi Akinaanu ati Oludele
Kunle, eni tawon eeyan tun mo si Otunba Jesu ti pade, ohun to si sele nibe fe
ma waye ri laarin awon olorin emi.
Nibi ijosin ti soosi ohun se laaro ana lawon laami-laka olorin
emi meta yii ti pade, opo wakati ni won fi korin papo lori itage, ti won n gba
ero agbagbe, iyen Microphone mora won lowo, ti awon eeyan si gbadun ara won
daadaa pelu imisi to sokale nibe.
Ohun ta a gbo ni pe, ki i se pe ile ijosin ohun gan-an ni in
lokan lati pe awon meteeta papo leekan naa ki won wa forin emi jise ihinrere
Olorun fawon eeyan, konge gan-an loro ohun je.
Purofeeti Adelagunja lo gba awon eeyan lalejo sibi ipago adura
ohun lojo naa, oun gan-an lo pe Oludele Kunle, eni tawon eeyan tun mo si Otunba
Jesu, nigba ti okan lara awon Pasito to wa sibe lojo naa ni ki Dare melody naa
wa forin emi yin Olorun. Bunmi Akinnaanu, iyen Omije Oju mi ni tie, ni ipade pataki
kan to fe ba Dare Melody se lojo naa ni, n ni won ba fipade sibe. Bi awon
meteeta se pade ree, ti won si jo forin emi jise ihinrere fawon eeyan to wa
nibi ipade adura ohun.
Ninu oro Otunba Jesu lo ti so pe, “Ohun to sele yii je ohun
iwuri, eyi to fi ife Oluwa han ninu aye wa. Ki i se ohun ti a gbero e rara, nitori
ki i se ohun to maa n saaba sele laarin awa olorin emi, ki a jo maa gba ero
amohun-dun-gbemu mora wa lowo. Ohun to dara ni o, to si le mu ojo ola orin emi
tubo dara ni Nigeria.”
O fi kun un pe, “Pelu ohun to sele nibe lana-an mo mo pe laipe
ohun nla kan yoo sele, ti yoo tubo mu irepo wa ati ilosiwaju laarin awa olorin
emi. Dare Melody naa so o lasiko to n korin wi pe, ohun ara otun kan n bo, bee
lo fidi e mule wi pe ileese rekoodu oun tuntun DM Multimedia n palemo lati se
bebe fawon olorin.
0 Comments