Bi awon lobaloba se peju, bee ni
igbakeji aare orile-ede yii atawon gomina pelu awon alenu-loro ti won je
gbajumo nla laarin ilu pejo, ti oju pe, ti ese pele. Ohun kan to si sele niluu
Oyo lojo naa ko ju ayeye nla ti Iku baba yeye, Oba Lamidi Atanda Adeyemi se,
iyen ogorin (80) odun lori erupe
Ojo keedogun osu kewaa odun 1938
ni won bi Oba Lamidi Olayiwola Atanda, bee baba to bi i, oba ni n se, oruko
baba ohun si ni Alaafin Adeniran Adeyemi keji. Olori Ibironke loruko iya
Alaafin Atanda, omo agboole Epo Gingin, ni Oke-Afin Oyo ni mama ohun n se. Omo
kekere patapata ni Lamidi Atanda wa, ti mama yii ti kanju gbona orun lo ni tie,
sugbon ori ti yoo la, Atari ti yoo dade, gbagbaa-gba, ni Olodumare maa n duro tiru
won.
Baba to bi Alaafin ni Adeyemi Keji lori ipo Alaafin Oyo, Olayiwola to wa lori apere bayii ni Oba Lamidi
Adeyemi Keta. Odun 1954 ni baba to bi Alaafin Oyo, kuro lori ipo, ote oselu ni
won fi han kabiesi leemo, sugbon nigba ti ori yoo se e, omo e, iyen Lamidi
Atanda lo tun pada joba lode Oyo, iyen lodun 1971.
Se nigba naa lohun-un, akowe
ileese adojutofo, insurance clerk ni Olayiwola Atanda n se, ki gbogbo Oyomesi too
ro oro oye kan an.
Ni tododo, oba nla ni Olayiwola
Atanda Adeyemi alowolodu-bii-yere, o gbajumo, bee lenu e tole daadaa gege bi
itan awon baba nla re ti won ti joba lode Oyo se ri. Nibi to je pe lasiko tiwon, nise ni won
fi isakoso won dari gbogbo ile Yoruba pata, lati Nigeria nibi, titi de gberi okun, lati
West ojohun ana titi de gberi osa, koda awon ara Dahomey, awon eeya Borgu paapaa mo pe, oba nla
ni Alaafin Oyo n se.
Iku Baba yeye, Atanda baba olopo
ibeji nile ti se ogorin (80) odun laye o, o fe ma si oba alaye ti ko wa, Ooni
Ile-Ife lo ko awon oba alaye yooku sodi wa ki Alaafin, bee Ojogbon Yemi Osibajo,igbakeji
aare orile-ede yii lo saaju gbogbo awon oloselu pata wa, yala APC, PDP atawon
egbe mi-in lorile-ede yii, gbogbo won ni won wa se baba ke e pe; fun ori ade. Adura
wa ni pe, eyi to ku ti Olayiwola Atanda yoo lo nipo, igba ile ko ni i fo o, bee
lawo ile lode Oyo ati ni Nigeria lapapo ati kaakiri agbaye ko ni i faya peregede bii aso...
0 Comments