GBAJUMO

IBO PAMARI PDP: ATIKU ABUBAKAR LO JAWE OLUBORI, WON NI OKUNRIN NAA YOO BA BUHARI FA A GIDIGIDI


Igbakeji aare orile-ede yii nigba kan, Alhaji Atiku Abubakar ti jawe olubori ninu eto idibo pamari ti egbe oselu PDP se niluu Port-Harcourt nipinle River.
Alaga eto idibo ohun, Ifeanyi Okowa, eni ti se gomina ipinle Delta lo kede e laaaro kutu oni, Sande, ojo Aiku.
Ninu oro e lo ti so pe ibo to le ni eedegbejo ati mejilelogbon (1,532) ni Atiku fi tayo awon yooku e bii Aminu Tambuwal toun ni ibo to fe to eedegberin-o-din-meje (693).
Eni to tun tele e ni Bukola Saraki to ni ibo oodunrin-o-le-metadinlogun (317);  Jonah Jang ni tie ni ibo mokandinlogun,  (19); Datti Ahmed ni ibo marun-un pere.
David Mark ni tie ni ibo marundinlogoji (35); nigba ti Tanimu Turaki ni ibo marundinlaadorin (65); Sule Lamido ni tie ni ibo merindin-logorun-un (96); Attahiru Bafarawa ni ibo mejidinlaadota (48); Ibrahim Dankwambo ni ibo mokanlelaadofa (111); Ahmed Makarfi ni ibo merinlelaadorin (74), nigba ti Rabiu Kwankwaso ni ibo mejidinlogojo (158).
Lara awon to ba a fa a
Bi nnkan se ri yii, Atiku Abubakar atawon oludije mi-in ni won yoo jo fa a lodun to n bo. Ohun tawon eeyan si n so bayii ni pe, ti egbe oselu PDP ba le duro ti okunrin yii, paapaa awon oludije yooku ti won fidi remi, eto idibo ohun yoo lagbara gidi gan-an, paapaa laarin Buhari ati Atiku lodun to n bo.  

Post a Comment

0 Comments