GBAJUMO

IDUNNU SUBU LAYO N’ILE-IFE *OONI LO GBE WOLII NIYAWO


Ooni Ile-Ife gbe arewa nla niyawo...nise ni gbogbo ilu n yo 
Ko seni to de aafin Adimula n’Ile-Ife lasiko yii ti ko ni mo wi pe ohun idunnu nla lo n sele nibe. Ooni-Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi lo segbeyawo tuntun, bee ojise Olorun ponbele niyawo to fe.
Laaaro kutu oni, ojo Eti, Fraide ni iroyin ohun gbalu kan wi pe iyawo osingin yoo wo Aafin oba loni-in, ojo Eti. Bi iwe iroyin se n gbe e, bee lawon eka iroyin mi-in ti won wa lori ero ayelukara naa n gbe e wi pe,
Kaabo sile ola, Ooni n ki Olori tuntun
Kabiesi ti gbeyawo tuntun, ati pe omo kekere patapata ni Yeyeluwa ohun n se.

Se ni nnkan bi osu merinla seyin ni ariwo deede gbalu wi pe iyawo Ooni Ile-Ife, Olori Zaynab Otiti-Obanor ti binu kuro laafin. Won lobinrin naa so pe, agbala oba ati gbogbo igbadun to n be nile Alase ekeji orisa ko wu oun mo, n lo ba ba tie lo.
Sa o, lasiko tawon eeyan si n ki Oluaye, iyen Ooni ku ayeye ojoobi odun kerinlelogoji (44), to pe lose yii; nigba yen gan-an ni kabiesi bo sori okan lara awon ikanni to fi maa n ba awon eeyan soro, iyen Instagram, nibi to ti kede e fun araye wi pe, oun ti niyawo tuntun o, bee Shilekunola, Moronke, Naomi Oluwaseyi loruko Olori ohun n je.
Oro ile ni won n se fun iyawo tuntun yii
Nibe yen gan-an lawon eeyan ti bere si ni dunnu, ti won si n ki kabiesi ku oriire.
Eni odun meedoogbon (25) niyawo tuntun yii n se, Wolii gan-an lopo eeyan mo on si nitori oun lo ni ileejosin kan ti oruko e n je EN-HERALDS, niluu Akure, nipinle Ondo.
Eni odun mejidinlogun (18) ni won so pe o wa to ti bere si ni se ihinrere nipa Oluwa, nigba ti yoo si fi deni odun mokanlelogun (21) o ti di ogunna gbongbo ninu ka polongo Jesu, ka si fi ise ihinrere jere okan fun Olorun alaaye.
Wolii, Moronke Silekunola, kaabo sile ola
Ju gbogbo e lo, Ooni Ogunwusi naa lomo kan tele o, Adeola Aanuoluwapo Ogunwusi loruko omo ohun n je, bee eni odun mokandinlogun (19) ni Kabiyesi wa, nigba to bi omo naa saye, eyi to tumo si pe, omo Kabiesi gan-an ti wa leni odun meedogbon (25) bayii.


Post a Comment

0 Comments