Pasito ijo Latter Rain, Tunde Bakare ti sapejuwe Alhaji
Atiku Abubakar, eni ti egbe oselu PDP fe lo fun idije-dupo aare lodun 2019 gege
bi eni to kunju osunwon, to si le koju Aare Buhari, toro ba doju ogbagade tan.
Ojise Olorun yii soro ohun ni soosi e lasiko to soro lori ayeye
ominira odun mejidinlogota ti orile-ede Nigeria se.
Bakare ti so pe, “Mo ki Atiku Abubakar ku oriire, bi egbe
oselu PDP se fe lo o fun idije-dupo aare, eyi yoo je ki eto idibo odun to n bo
larinrin daadaa.
“Mo gbagbo wi pe Aare Muhammed Buhari naa yoo lo ipo e gege
bi adari orile-ede yii lati fi sise daadaa si i ko le rorun fun un lati pada wa
leekan si i. Bee ni mo tun nigbagbo wi pe, Atiku Abubakar naa ko ni i gba a
lero, nise ni won yoo jo na an tan bii owo. Eni to to gba-n-gba sun loye lawon
mejeeji, eyi gan-an ni yoo mu idibo odun 2019 larinrin.”
Pasito Tunde Bakare te siwaju pe, ki i se pe oun n lukoro
fun un, sugbon ti a ba n so nipa eni to kunju osunwon daadaa laarin awon ti won
jo dije pamari, ati pe Atiku Abubakar ni enu e tole daadaa laarin gbogbo eya
meteeta ti ede won han ju ni Nigeria, iyen WAZOBIA.
O wa fi kun un oro e wi pe, “Awon araalu ni yoo so ibi ti won
fe lo lori awon mejeeji nitori yoo soro lati so pe Atiku ni yoo jawe olubori
tabi fidi remi ninu ibo ohun, nitori eni ti iriri e kun daadaa ni. Akoko, o ti
lo odun mejo ri gege bi igbakeji aare orile-ede yii, bee lo tun je omoleyin
Yar-Adua, to si n tele ilana ti iyen fi sile.”
Bakan naa lo tun so
pe, onisowo to ti gbiyanju daadaa ni okunrin naa n se, ti a ba n so nipa keeyan
o mo nipa oro aje.
Siwaju si i, Bakare so pe, “Awon abuda ti mo so soke yii
nikan ko lo maa n mu eeyan jawe olubori ninu ibo o, nitori ohun to wa leyin efa
ju eje lo daadaa.”
Okunrin ojise Olorun yii ti wa ro awon omo egbe oselu PDP
lati mura daadaa ki won si je ki awon omo Nigeria mo pe won ti tuuba ninu iwa
ajebanu, ati pe isoro ti won ko awon omo orile-ede yii si fun odun merindinlogun
ti won fi sejoba Nigeria, iru igbe aye bee ko tun ni i waye mo.
Lori egbe oselu APC, Tunde Bakaere so pe ki i se pe oun
korira egbe naa, o ni, loooto ni joba n gbiyanju, sugbon bi won se so pe awon n
sise to, sibe opo eeyan orile-ede yii ni won n pariwo, ti ara n ni awon eeyan
gidigidi. O ni, igba die to ku ki eto idibo mi-in waye yii, nise ni won gbodo
lo anfaaani die to ku lati fi sise ki irorun ati idekun le ba awon eeyan Nigeria
, ki nnkan le senuure fun won lodun 2019 ninu ibo to n bo.”
Lakootan, Bakare ti so pe asiko niyi fun gbogbo omo Nigeria
lati yan olori ti yoo ko irorun ba won, ti igbe aye won yoo le ni ilosiwaju
rere bi eto idibo se n sunmo etile yii.
0 Comments