![]() |
Sup. Evang. Prophet Michael Adekunle a.k.a Olorundarapupo |
Sannde to n bo yii ni ile
ijosin Celestial Church of Christ, New Jerusalem Parish yoo sajodun ikore ati
idupe; eyi ti se eleekeedogun ti Ile ijosin ohun yoo se.
Ninu atejade ti Oluso ijo naa, Sup.
Evang. Prophet Michael Adekunle a.k.a Olorundarapupo fi sowo si wa lo ti salaye
pe, “Ikore ati isin idupe t’odun yii, akanse lo je, nitori a fe fi emi imoore wa
han si Olorun alaaye to se ohun rere lopolopo ninu aye awa omo olu ijo mimo. Idi
niyen ti a fi pe e ni ikore igbega latowo onise iyanu. Nitori e gan-an la se fe
ki gbogbo eeyan o wa pelu wa ninu oriire nla yii.”
O te siwaju ninu oro e pe, “Loni-in
ojo Aje gan-an leto ti bere, ose kan gbako la fe fi se e. Isoji la o fi bere loni-in
ni deede aago merin. Eni ti yoo fi ounje emi bo awon omo ijo Olorun ni Sup.
Evang. PRO Fasasi ninu soosi wa gan-an leto ohun yoo ti waye. Bakan naa ni isoji
yoo tun te siwaju lojo Isegin Tusde, ni deede aago merin irole, soosi wa ni eto
ohun yoo ti waye pelu. To ba di lojo Wesde laarin aago mesan-an asale si aaro
ojo keji, akanse eto yoo wa fun gbogbo awon ti won n sebeere, iyen awon odo wa.
Nigba ti akanse eto nipa ilera ofe yoo waye lojo Tosde laarin aago mewaa aaro
si merin irole, asale iyinlogo lo maa waye lojo Fraide bere lati aago mesan-an
ale, nigba ti a o maa seto ipalemo ikore lojo Satide ni aago mewaa aaro. Ojo
Sannde to n bo yii gan-an ni asekagba ikore nla yii, nibi ti a o ti se isin
idupe, bere lati aago mewaa aaro.”
Wolii Olorundarapupo ti so ninu
oro e pe, soosi ohun to wa ni 15b Segun Allen street, Segun Allen Bus stop, of Ojokoro
Road, Eyita Ikorodu l’Ekoo ni gbogbo eto ohun pata yoo ti waye.
Lara awon alaga ikore ni A/LRD
Seyi Oderinde; Bro. Tosin Adamolekun;
L/S Osinuga atawon eeyan pataki mi-in. Lara awon eni ami ororo ti yoo wa nibi
asekagba eto ohun ni; Sup. Evang. Badmus; Sup. Evang.M.A Omolade; Sup. Evang. Abilagbo;
ALRD Seyi Oderinde; Sup. Evang. M.O
Oduyebo ati bee bee lo.
0 Comments