GBAJUMO

ILEESE YEFADOT ATI BANKI FCMB SEPADE PELU ARAALU *WON LAWON YOO YA AWON AGBE ATAWON ONISE OWO MI-IN LOWO


Pitimu lero kun ileese YEFADOT l’Ojodu Berger l’Ekoo laipe yii nigba ti won lo pade ileese banki FCMB atawon ileese mi-in lori bi won yoo se ri owo ya, tawon onisowo keekeeke naa yoo lo rowo fi sowo lawujo.
Oloye Yetunde Babajide to gbalejo awon araalu ati banki FCMB yii lo koko sipade lojo naa pelu oro iyanju fawon eeyan. Ninu oro e lo ti so pe, “Ohun to se pataki fun wa lorile-ede yii lasiko yii ni bi kaluku yoo se san sokoto e ko le, ki ojo ola wa le dara. Ijoba Buhari setan lati ran wa lowo, bee lawa gan-an paapaa ko gbodo sole, nitori e ni ileese YEFADOT se gbe eto ekose owo kale lorisirisi. Ise agbe je ohun kan pataki ti a mu ni okunkundun, bee lawon ise mi-in ti eeyan le ko wa lorisirisi ti a n ko awon eeyan nibi.”
Awon osise banki FCMB
Iyalode Ojodu yii ni asaaju awon obinrin nile Yoruba ninu egbe to n sepolongo ibo fun bi Aare Buhari yoo se tun sejoba leekan si i, iyen Woman Leader South-west, Buhari Support group. Ninu oro e lo ti so pe koko ohun ti oun maa n tenu mo ni gbogbo igba ti oun ba ti lanfaani lati ba Aare Muhammed Buhari sepade ni bi awon araalu, paapaa awon mekunnu yoo se ri tiwon se ninu ijoba e. O ni, “Orisirisi eto amayederun ni ijoba to wa nibe lasiko yii ni fun awa araalu. Ijoba eleyii, ti mekunnu ni o, bee lo koriira ajebanu, gbogbo ohun ti ko ba to, e o le ba emi nibe. Bakan naa ni Aare Buhari gan-an ko ni i fowo si i, nitori e ni oro emi e se wo daadaa. Gbogbo awon obinrin wa pata ni anfaani ti wa fun bayii, a o ko yin nise owo, bee la o seto bi e o se ri owo ya lowo banki, lona ti ko ni i ga yin lara. Ijoba Buhari lo gbeto yii wa o, nitori e ni mo se ro n wa wi pe a o ko gbodo so ibo wa nu, ti asiko a ti dibo ba to. Ni ti ka ni aniyan rere fun ilu, egbe oselu APC lo le se e fun wa, Aare Muhammed Buhari si leni naa ti o le mu aye awon eeyan orile-ede yii rorun. Awon ti won n da agbada kiri yen, e ma da won lohun o, won tun fe ko eyin eeyan wa sinu ajaga mi-in ni.”
Lara awon araalu ti won wa
Gbajumo oloselu yii ti fidi e mule wi pe, ijoba apapo ti gbe eto eyawo kale fawon olokoowo alaboode, eyi ti yoo je ki ilosiwaju tete ba orile-ede wa, bakan naa lo fi kun un pe, awon eeyan ti oun n ko jo, o ni ona lati gbon ise ati osi danu lo je oun logun. Bee ni Iyalode Ojodu ti bu enu ate lu bi awon eeyan se maa n sare tele awon oloselu nitori awon nnkan keekeeke ti won maa n pin le won lowo. O ni, “Ohun ti mo korira ju ni ki eeyan maa toro owo kiri lowo oloselu, ti awon naa a maa fun awon eeyan ni nnkan ti ko le tan isoro won. Lodo tiwa nibi, awa ki i pin owo, bee la o ni i pin agolo iresi, ohun ti a n se fawon ti won ba ti darapo mo wa ni bi a o se ko won nise owo, tawon naa yoo kosemose, ti won a le da duro Bee ko tan sibe o, a o seto bi e o se rowo sowo, eyi gan-an ni orile-ede fi le ni iloswiaju. Ki i se ki oloselu maa pin owo ti ko to fi jeun lojumo le awon eeyan lowo, eleyii ko ni ibi kankan to le gbe eeyan de, eeyan kan maa wa loju kan ni, iru nnkan ti ijoba Buhari ko fe niyen. Gbogbo wa lo jo gbodo la, ti a gbodo soriire ninu ijoba yii o, bee owo wa lo wa. Idi e niyen, ta a fi ni ki kaluku foruko ileese e sile. Pelu egberun marun-un naira, eyin naa le di eni to maa nileese, ti e o si gba eeyan sise pelu. Iru nnkan to maa n mu orile-ede te siwaju niyen.”

Lara awon to tun wa nibe lojo naa ni asoju ileese to maa n foruko awon ti won ba fe da ileese sile, iyen Corporate Affairs Commision, bee lawon osise banki FCMB naa wa nibe pelu lati la awon eeyan loye.

AWON OSISE BANKI FCMB NAA SE IDANILEKOO FAWON EEYAN LOJO NAA, E WO FIDIO YII…..



Post a Comment

0 Comments