GBAJUMO

IPARA IGBALODE TO LE MU ARA JOLO TI KO NI KEMIKA NINU NILEESE WA N SE- REMI OJEBIYI


“Ki igbe aye irorun le ba awon eeyan kaakiri agbaye nipase itoju ara atawon ohun to le mu ara dan, ti yoo si tun mu ara jolo, eyi gan-an lo mu wa da ileese Moshea Glance sile.”
Arabinrin Remilekun Ojebiyi, obinrin onisowo, omo Nigeria to fi orile-ede America sebugbe lo soro yii. O ni, “Ohun kan to je ileese wa logun ni ipese ipara awon alafe gbogbo.
“Yato si eyi, a tun lawon ipara orisirisi to le koju kokoro ati aisan abanilawoje bii ifo, lapalapa, alefo, isaka, tanmona ati bee bee lo, to maa n ba awon eeyan ja lago ara. Awon eroja asaraloore ni a ko jo, eyi ti ko ni kemika kankan ninu la fi se ipara oloorun adidun yii
“Fun gbogbo eeyan to fe pupa foo, ti won fe maa dan gbinrin bii oyinbo, tabi eeyan to fe ki dudu oun maa dan, ko si maa dara si i, gbogbo e pata la ni nikawo wa, ko si iyonu tabi wahala kankan fun won mo, gbogbo eyi pata lawa ti seto e nileese wa pelu awon eroja asaraloore, eyi ti a mu ninu awon ohun alumoni ti ko ni kemika kankan ninu.”

O fe ma si eroja amunidara, ti ileese Moshea Glance ko ni nikawo, bi won se ni eyi to n so eeyan di oyinbo, bee lawon mi-in tun wa to le tun awo eni to ti ginran patapata se, ti tohun yoo maa dan gbinrin bii  oyinbo, ti ara eeyan ko ni i yi, ti eeyan yoo maa dan jolo. Omi-in to tun wa naa ni eyi ti eeyan le fi pa igunwo to ti giran, oju ti apa kan dudu, ti apa kan pupa latari ipara oloro tawon eeyan ti fi pa oju tabi ara won ri, gbogbo nnkan wonyi lo n ti ileese won jade.

“Orile-ede USA, iyen Amerika lohun-un ni a ti pelo e, ohun ta a mu latara eso ati ojulowo ohun asaraloore la fi se e. Kaakiri lawon ipara asaraloore yii ti wa bayii, bi o se wa ni America lodo wa nibi, bee lo wa ni Nigeria, ti a si tun ni in ni ilu London atawon ibomi-in kaakiri.” Remilekun lo so bee.








Post a Comment

0 Comments