GBAJUMO

ISE ASOFIN KI I SE FAWON AGBEJORO NIKAN- JIDE JIMOH


Lati ni awujo ti eto ofin e yoo wulo fun araalu, ti idagbasoke olokan-o-jokan yoo wa pelu, Onarebu Jide Jimoh ti so pe, ki i se awon agbejoro nikan lo ye ki won wa nile igbimo asofin.
Lori eto kan lori radio ni Onarebu Jide Jimoh, to n soju ekun idibo Lagos Mainland Federal Constituency ti soro yii lana-an nigba to n soro lori akori yii, Ti awon agbejoro ba po daadaa nile igbimo asofin, nje eyi le mu agbekale ofin to yaranti wa bi?
Okan lara asoju-sofin niluu Abuja yii ti so pe, “Ti a ba n so nipa agbekale ofin, awon eeyan to ba nimo kikun lo ye ki won wa nidii e, bee ki i se awon agbejoro nikan, orisirisi eeyan ti won ni iriri kikun ninu orisirisi ise lo ye ki won wa nile igbimo asofin. Eyi gan-an ni yoo fun awujo wa ni eto ofin to peye, nitori kaluku ni yoo lo iriri e lati fi se aato ilu.”
O fi kun oro e wi pe, "Gege bi asofin, o pon dandan ki eeyan dije dupo ohun, bee lawon oludibo naa ni ojuse tiwon lati yan eni to ba wu won sipo, irufe eni ti won fe ki o lo soju won nile igbimo asofin yii le je onimo-isiro, o le je oluko, tabi onimo ero, awon araalu ni won yoo so eni ti won ba fe pelu ibo won.
“Bee ise ofin ni se pelu agbekale aba eyi ti yoo pada dofin, bakan naa tun ni jije asoju awon araalu ti a lo soju fun nibe. Ko tan sibe o, ojuse asofin naa tun ni lati ri i daju pe ise ilu ti won gbe fawon kongila, won se e bo ti to ati bo se ye, eyi gan-an lo le mu idagbasoke ba ilu atawon araalu paapaa.”
Siwaju si i, Onarebu Jimoh ti so pe ki i se gbogbo eeyan to kekoo nipa imo ofin naa lo maa n sise agbejoro, ati pe eni to n sise agbejoro daadaa yoo wulo gidi nipo asofin.
O wa fi kun un oro e pe ko si ise tabi imo ijinle ti eeyan ni ti ko wulo gege bi asofin, yala eeyan je agbejoro, osise banki, tabi awon ise mi-in ti eeyan ba kawe gboye ninu e.
O ni, “Nile igbimo asofin, a lawon agbejoro, ti won ko fi bee ko ipa gidi to awon ti ko tie kekoo gboye imo ofin toro ba doro ofin. Elomi-in ninu  won paapaa ko le so pe abadofin kan bayii loun ti gbe siwaju igbimo asofin ri, bee la ni awon dokita to je pe ojulowo ni won, ti a ba n so nipa igbekale ofin lorisirisi to le mu orile-ede yii te siwaju. Ohun to se pataki ni ki eeyan ni imo kikun nipa ise kan, eyi si le mu irufe eni bee se daadaa ju eni to kawe gboye imo ofin lo. Ohun to tun se pataki ni bi eeyan ba se ni akikanju ati imo kikun si.
O ni, ti eeyan ba je amofin, iyen ko so o di asofin, nitori pe o lawon igbese ti yoo waye ki eeyan to le pe ara e ni asofin, ati pe owo awon araalu to maa dibo yan iru eni bee lo wa, ati egbe oselu to maa fa a kale.
Osise banki ni Onarbu Jide Jimoh tele ko too darapo mo oselu. Ohun to si so ni pe, “Ko ise tabi imo ti eeyan ni ti ko dara, yala eeyan je osise banki, tisa, agbejoro tabi dokita ti oro ba di bi ki asofin, ohun ti mo mo ni pe, imo kaluku ati iriri to ba ni, ti a ba pa a po, eyi gan-an ni yoo fun wa ni agbekale ofin to le se awujo lanfaani ti ara yoo le de mekunnu paapaa.

Post a Comment

0 Comments