Gomina Rauf Aregbesola ti
sapejuwe iwode ti alaga egbe oselu PDP atawon omo egbe e se lo si olu ileese
ajo INEC l’Abuja gege bi iwa were, ti ko si fi won han gege bi eni ti ara e ya
rara.
Lasiko ti Aregbesola n ba awon
oniroyin soro lofiisi Aare orile-ede yii lo soro ohun. O ni, bi won se ko ara
won sinu moto ajegboro, ti won n sewode kaakiri Abuja yen fi won han gege bi
eni to ni aisan opolo. Gomina yii tun fidi e mule wi pe, moto to ti lo patapata
lawon omo egbe oselu PDP n juwo si, nitori pe Gboyega Oyetola ni yoo gba ipo
lowo oun laipe yii.
Lati fehonu won han lori
abajade esi ibo to waye nipinle Osun, ninu eyi ti egbe oselu APC ti jawe
olubori, ti PDP si fidi remi, eyi lo mu egbe oselu PDP sewode lo si ileese ajo
INEC niluu Abuja loni-in.
Alaga egbe naa, Uche Secondus,
Bukola Saraki, Yakubu Dogara atawon laami-laka mi-in ninu egbe naa ni won jo wa
ninu moto ajegboro ti won n gbe kiri Abuja.
0 Comments