Okunrin omo Ilesa yii ti ba
Magasinni yii soro. Lati orile-ede Amerika to wa gan-an lo ti pe wa, ninu eyi
ti a ti se iforowanilenuwo fun un lori ise sinima to so o deeyan nla ati bi ise
sinima Yoruba se n tan kaakiri agbaye bayii.
Oruko mi ni Sunday Olamilekan
Ojo, omo Ilesa ni mi nipinle Osun. Oruko baba mi ni Ajagun-feyinti Oladosu Ojo,
nigba ti iya mi n je Olufunke Ojo.
Ipo kerin ni mo wa ninu awa
marun-un ti iya mi mi bi. Seventh day Adventist Primary school loruko ileewe alakoobere
ti mo lo ni Agodi gate n’Ibadan.
Bakan naa ni mo kekoo girama mi
ni Basorun Ojo High school ni Orita Bashorun.
BI MO SE BERE ERE ORI ITAGE
Lati ileewe alakoobere mi ni mo
ti koko bere ere ori itage, sugbon nigba to di odun 1982, mo darapo mo egbe
osere kan n’Ibadan.
Lara igbiyanju wa nigba yen ni
sinima kan ti a fe se fun ileese BCOS n’Ibadan, ni kete ti won da ileeese
telifisan ohun sile nigba yen, sugbon latari idiwo kan tabi ikeji, a o le se e
fun won.
Nigba ti mo de Eko, mo gbiyanju
lati te siwaju nidii ise ohun. Nigba to di odun 1990, mo salabapade egbe kan to
je ere ori-itage nikan ni won yan laayo, won ki i se sinima, MASCOTT Troupe
loruko egbe naa.
Kaakiri awon adugbo la maa n
gbe ere ori-itage lo. Leyin odun meji ti mo darapo mo won leni to ni in gbiyanju
lati te siwaju, bo se gba Port-Harcout lo niyen.
Bo se lo tan, ni mo tun ti bere
si wa ibomi-in ti mo tun ti le maa lo ebun nla ti Olorun fun mi yii, nigba ti
Olorun si maa se e, okan ninu awon oga to n kose mi nise, nibi ta a ti n sise
mekaniiki lo maa n mu mi lo si National Theatre nibi ta a ti n lo ba won ta
tikeeti.
Nibe gan-an ni mo ti pade
okunrin kan ti won n pe ni Segun Philips, okan lara awon omo iya Rainbow ni,
oun gan-an lo fa mi le enikan lowo ti a n pe ni Arupe.
BI MO SE DE ODO OGA BELLO ATI OHUN TI MO GBO
Arupe yen lo mu mi de odo oga
ti mo ti kose ere ori-itage. Oruko oga mi ni Adebayo Salami, eni tawon eeyan
tun mo si Oga Bello. Oruko tawon obi won si maa n pe won ni Oba.
Odo Oga Bello ni mo ti kose fun
odidi odun marun-un gbako bo tile je pe adehun wa, odun meji pere ni mo so pe
maa lo.
Ohun to sele ni pe, bi mo se
darapo mo egbe osere won, orisirisi nnkan ni mo gbo lenu awon eeyan lati ita.
Se e mo pe ti eda ba maa soriire, awon eeyan maa n wa ona ti won a fi se tanadi.
Orisirisi nnkan lawon eeyan n so, won so pe nibi ti mo ti lo kose yen, ko si
eeyan to kose nibe to soriire ri.
Bee ni temi, lati kekere mi ni
mo ti nigbagbo gidi ninu Olorun, mo ba Eledaa mi soro, mo ni to be je pe loooto
lohun ti won n so yii ba ri bee, mo be o, je ki temi o je opin.
Je ki emi le saseyori lodo oga
mi. Mo tun wa be Olorun wi pe, ti mo ba se aseyori nidii e tan, ma je ki n wa
nipo eni ti a maa so pe, bi e o tie pe mi sise, mo ti de!
Ohun to sele ni pe, mo ti ri
arisa awon to n seru e, bee mo mo bi egbin se maa n kan won lopo igba.
Nigba ti odun meji ti mo
sadehun e pelu oga mi pe, mi o ri ami ati ise iyanu wi pe Olorun ti gba adura
mi, bi mo tun se fi kun odun ti maa lo lodo won niyen. Nigba ti odun marun-un
pe, iyen lodun 2004, lasiko yen gan an ni Olorun jewo agbara e, o gbo adura mi.
Emi naa gba ominira lojo kerinlelogun osu kewaa, odun 2004.
Ojo keji e, iyen ji keedogbon
osu 2004 ni mo bere sinima temi gan-an, oruko sinima mi akoko ni Ojo oro, leyin
e ni mo tun se opolopo bii Emi nire kan; Wonyosi, Salaye ati opolopo. Gbogbo
fiimu mi a fe to merinla.
AJOSEPO EMI ATI SAIDI BALOGUN
Awon eeyan pataki ti mi o le
gbagbe ninu irin-ajo yii ni Lasun Ray; Murphy Afolabi; Saidi Balogun.
Yato si pe mo kose lodo oga mi,
Adebayo Salami, enikan ti oun naa se daadaa si mi nidii ise yii ni Saidi
Balogun, o duro gege bi ore, bee lo satileyin fun mi gege bi oga. Bakan naa lo
tun pelu mi gege bi eni ti a n foju jo ninu ise sinima.
Titi aye, mi o le gbagbe awon
eeyan ti mo daruko yii.
IRUFE OBINRIN TI MO FE
Iyawo mi ki i se osere tiata,
sugbon eni to nifee si ise ti mo n se ni, se nibi ti ife ba ti wa, gbogbo ohun
ti ololufe eeyan ba ti n se, nise leeyan maa n gbarukuti i.
Nigba ti adojuko nla de, ti
irewesi okan fe sele, ohun ti iyawo mi so fun mi ni pe, sebi e so pe ohun ti e
yan laayo le n se yii, to ba ti wa je bee, eyin e tera mo on. To ba je nipa ti
awon omo, agbara Olorun a gbe e!
OJO LOJO TI MOTO MI JONA…
Lodun ti iya mi, Iya Awero, ti
oruko won n je Taiwo Hassan se sinima won akoko, ti oruko re n je Aayo Okan,
ojo yen ni mo koko ri adojuko, ti won ba so pe eeyan ri adojuko nidii ise yii.
Lojo naa, sadeede ni moto mi gbina, gbogbo igbiyanju wa lati fi omi pa a lojo,
pabo lo ja si!
Gbogbo bi awon eeyan se n ba mi
fomi pa a, nise ni mo n rerin-in, tawon eeyan si n wo ara won loju wi pe, ki lo
n pa mi lerin-in, awon mi-in ro pe boya nnkan ti yiwo fun olodi mi ni. Ohun ti
emi si n rerin si ni pe, mo dupe ti mi o jona mo moto, ayokele lo jona o, omo
Ojo ko jona!
Lojo naa, o kuku lohun ti mo ba
Olorun so, mo ni bi won se maa n so pe ko si ki eeyan wa ki o ma ri adojuko,
iwo Olorun mo ti ri adojuko temi, leyin eleyii, ayo ni mo fe.
Ti a ba n so nipa ere sinima
lasiko yii, iyato nla ti wa, ise wa n lo siwaju bee lawa ti a n se paapaa; igbe
aye wa ti yato si ti tele. Onitiata ti n lanfaani lati lo moto nla ninu ere,
bee irufe moto yen, oun lo ni in o,
bakan naa ni ile nla nla, gbogbo ohun wonyi, aseyori tom ba ise yii ni, a si dupe
lowo Olorun to je ki o siju emi wa, aleekun oore la n fe lopolopo.
ASEYORI MI NIDII ISE YII
Gbogbo igba la n dupe fun oore
ti Olorun n se, bee ni mi o fi igba kan banuje ri, nitori ise ori ran mi ni mo
n se, ona Edumare la kale fun mi ni mo n to. Ki Olorun tubo je ki a le maa
rerin-in ayo nidii e.
BI MO SE GBE ANTP WO SOUTH
AFRICA
Lodun 2013 ni mo koko rin
irin-ajo lo si orile-ede South Africa, okan lara awon osere akegbe mi ni Olorun
lo fun mi lodun naa, Alhaja Nike Peller. Nigba ti mo de ohun, mo ri wi pe awon eeyan
wa n se daadaa ninu ise sinima, bi mo se pe won jo niyen, ti mo si gba won
niyanju wi pe ki a da egbe awa osere tiata sile. Won gba si mi lenu, bi a se ni
egbe ANTP nibe yen, sugbon leyin odun meji, egbe ohun ko se deede mo. Bi mo se
tun pada lo niyen, ti mo lo fi egbe TAMPAN, iyen egbe awa osere lole. Gbogbo
won ni won tewo gba a lowo mi. Awon eeyan bii Ogbeni victorist; Omooba Fubes;
Ogbeni Fred, Ogbeni Adebowale, eni tawon eeyan tun mo si Gunshot; Otunba Olufemi Jaiyesinmi to ni Luliluli
Hotel; Otunba wale Balogun; Arabinrin Matoldi ati emi naa. Leyin e ni a se
agbekale ajo kan Theatre art and music video African awards (Tamvaas Award),
ohun ti ajo yii wa fun ni lati maa fun awon eeyan to n se daadaa lenu ise won,
ti won tun n se koriya fun gbogbo ohun to ba ni se pelu amuludun ni awoodu. Gbogbo
awon eeyan pata ti won ni ohun kan tabi mi-in se po sinima la ko jo sinu egbe
yii. A ti seto awooodu meji, a se akoko lodun 2016, bee la tun semi-in lodun
2017, odun 2019 la n mura e sile bayii
IMORAN MI FAWON TO N BO LEYIN
Imoran mi fun awon to n bo
leyin ni pe, ki won kun fun adura, ki won bowo fawon ara iwaju, ki awon naa le
m’oke. Bee ni mo tun ro won, ki won fi igbagbo won sodo Olorun nikan, nitori
oun nikan lo le so eeyan di irawo nla. Kuro nibe je ki won ri mi, asiko eeyan
ko ti i to ni o, to ba je iwo lo kan ti asiko e ba to, won a kuku nawo si e.
Bakan naa ni mo tun fe ro won,
to ba di pe aye ti n mo won, ki won ma joye onigberaga, won gbodo ko bi eeyan
se n fi omoluabi lo irawo to ba ni. Nitori okiki lagbara pupo, ti eeyan ko ba
sora, ki eeyan fi omoluabi lo o, o le so eeyan di alabuku nigbeyin.
Ati pe ounje ta a ba je, ti a
ba fi warawara je e, a maa sa pa ni lori.
0 Comments