Pitimu lero pe ni gbongan nla TIMES SQUARE n’Ikeja l’Ekoo lana-an
ojo Satide, ojo kefa osu kewaa nibi ti gbajumo onitiata meji ti segbeyawo
alarinrin.
Okiki Afolayan, eni tawon eeyan mo gege bi adari ere sinima
Yoruba lo segbeyawo pelu Abimbola Ogunowo, okan lara awon osere Yoruba, to n se
daadaa lasiko yii. Awon mejeeji yii ni won dana ariya nla l’Ekoo, gbogbo osere
tiata pata lo wa, bi awon ti won pe daadaa lenu ise ohun se wa, bee lawon to
sese bere naa ko gbeyin, ti oju pe, ti ese si pele pelu.
Bi eto ti bere, ti ero agbagbe, iyen micro-phone n dun
kikan-kikan, bee lawon osere n ya wo inu gbongan nla yii. Bi awon ti won wa ni
Nigeria se wa pelu aso ebi lorisirisi, bee lawon to n gbe niluu oyinbo bayii
naa wo baluu wa, ti won si wa ye Okiki ati iyawo e tuntun yii si.
Awon Afaa ni won koko seto lowo aaro, Nikai, iyen igbeyawo
nilana esin Islam lo koko waye, se musulumi gidi ni awon obi iyawo, Abimbola
Tawakalitu Agbeke. Bi won ti so won papo tan loko ati iyawo ti lo parada, ti eto
idana, iyen Marriage Engagement naa bere ni pereu, nibi ti awon alaga iduro ati
ti ijokoo ti se bebe lana-an.
Lasiko yii, awon osere nla nla bii Yinka Quadri ti wa
nikale, bee ni Fathia Balogun, Sikiratu sindodo, Opeyemi Ayeola, Rafiu Balogun,
Regina Chukwu, Funso Adeolu Adegeye atawon mi-in ti wa nitosi.
Bi eto yii se n te siwaju, bee lawon osere tiata n ya de bii
omi, tawon ololufe awon onitiata mejeeji yii pelu atawon molebi pelu awon
alabase naa ko gbeyin.
Leyin ti ayeye idana ti pari ni eto igbeyawo ohun kan ayeye
iweje-wemu, nibi ti awon eeyan ti jeun, a-je-yo, ti won tun mu nnkan lorisirisi
pelu.
Lojo naa, awon maketa naa koo gbeyin o, aso funfun olowo nla
ni won wo wa, lara won ni Alhaji Abdulahi Abdul-Rasaq, eni to nileese Corporate
Pictures, Okiki Films, Oloye Sunday Esan, bee ni Ogbeni Kazeem Afolayan to ni ileese
Epsalum ati Kazeem Adeoti, iyen Adekaz naa wa nibe pelu atawon mi-in ti won je
oloruko nla nidii ise kara-kata sinima, paapaa sinima lede Yoruba ni Nigeria.
Awon osere tiata,
kaakiri ile Yoruba naa wa o, bi awon ara Eko se yoju sibi inawo ohun lopo yanturu,
bee ni awon osere nla nla lati Abeokuta lodo awon Segun Ogungbe, Odunlade
Adekola, Bukola Adeeyo, Arinola Ajao atawon mi-in naa wa nibe.
Opeyemi Ayeola lati London naa wa, Biola Adebayo, eni ti
awon eeyan tun mo si Biola Eyin-oka wa lati Canada, bakan naa lawon osere nla
nla bii Fausat Balogun, Jumoke George, Fathia Balogun, Sikiratu Sindodo, Mercy
Aigbe, Kemi Afolabi,. Kemi Korede, Bimbo Oshin, Femi Adebayo atawon aburo e,
Ibrahim Chatta, Murphy Afolabi, Mide Martins Abiodun, Tolani Osinrin ati bee
bee lo, bee ni Dayo Amusa forin ife da toko-tiyawo laraya.
Yato si eyi, orisirisi aso lawon osere tiata yii mu fun
inawo nla ohun, bi awon ti won je ore oko se mu aso alawo ewe, bee lawon ti won
je adari-ere nidii ise tiata, iyen darekito naa mu aso tiwon loto. Ninu won ni
Adebayo Tijani, Hafeez Owoh, Kunle Afod atawon mi-in.
Ninu imoran ti alaga ojo naa, Ogbeni Sunday Esan to nileese
Okiki Films fun toko-tiyawo ni pe; ki won nigbagbo ninu ara won, ki won si yera
fun ohun to le da igbeyawo ru. O ni, o se pataki ki igbeyawo naa laseyori, sugbon
bi yoo se m’oke, ti ituka ko ni i si wa lowo awon mejeeji.
Funso Adeolu ati Ijebu, Tayo Amokade lo dari eto lojo naa,
bee ni olorin wa, ti D.J paapaa se bebe lojo naa.
0 Comments