Fraide ojo Eti to koja yii lawon omo egbe oselu PDP jade
lopo yanturu, ofiisi ajo INEC ni won kora won lo, bee ni won tun ya si olu
ileese olopaa pelu, ohun ti won si n beere fun ni bi ajo eleto idibo yoo se
kede Ademola Adeleke gege bi gomina nipinle Osun.
Ohun ti alaga egbe oselu PDP, Uche Secondus n beere fun niyi
pelu awon laami-laaka oloselu inu egbe naa bii Dokita Bukola Saraki, Dino
Melaye, Yakubu Dogara, Rabiu Kwakwanso atawon mi-in ti won jo sewode ohun
kaakiri Abuja.
Sugbon, ileese olopaa ti so oro ohun di bami-in mo won lowo
bayii. Oga agba patapata fawon olopaa lorile-ede yii, Ibrahim Idiris ti so pe
ki won sewadii ohun to da wahala sile lasiko ti won sewode ohun, ati pe Saraki,
Dino Melaye ati Seneto Muray Murray Bruce gbodo yoju si olu ileese olopaa naa
lojo Monde ki won wa so tenu won.
Lara esun ti won ka si won lese ni pe won da wahala sile
lojuna Shehu Shagari niluu Abuja, won ni won tun di alaafia ilu lowo, bee ni
won tun ba nnkan je nileese olopaa ti won se iwode lo.
Saaju ki ileese olopaa too so pe awon omo egbe oselu yii
gbodo yoju si ofiisi awon lojo Aje Monde, lawon Dino Melaye naa ti pariwo sita
wi pe iya nla ni ileese olopaa fi je awon lori bi won se yin tajutaju lu won
lasiko ti awon n se iwode ifehonu han oniwoorowo.
Alukoro fun ileese olopaa, Jimoh Moshood ti so pe, “Oga agba
patapata fun ileese olopaa ti pase wi pe
Seneto Bukola Saraki, Dino Melaye ati Murray Bruce gbodo yoju sileese wa lojo
Monde, esun ti won fi kan won ni pe, won n da alaafia ilu laamu, bee ni won tun
ko awon eeyan sodi lati maa fehonu han kaakiri, ninu eyi ti won ti da
sunkere-fakere oko sile lojuna Shehu Shagari niluu Abuja. O ni eyi lodi si ofin
pupo, won si gbodo wa salaye enu won nileese olopaa lojo Aje to n bo yii.
Awon omo egbe oselu PDP yii ti fi ehonu won han lori igbese
ileese olopaa lasiko ti won se iwode ohun. Murray Bruce ni tie bu enu ate lu
ohun tawon olopaa se lori bi won se yin tajutaju lu won, bakan naa ni Dino
Melaye naa so pe, ohun abuku ni bi awon olopaa se n lo aso mo oun lorun, ti won
si fiya je oun lori pe oun fehonu han lona ti ko lodi si ofin rara.
Nibi ti won yoo gbe oro yii ka, gbogbo e pata di ojo Aje to
n bo yii nigba ti won ba de ileese olopaa l’Abuja.
0 Comments