Were bayii loro ohun
bere, bii awada bii ere lopo eeyan si pe e, paapaa laarin awon osere ti won jo
n sise sinima, sugbon ni bayii, Okiki Afolayan ti gbe Bukola Tawakalitu Ogunowo
niyawo, igbeyawo alarede ni paapaa.
Tosde, ojo kerin osu yii
gan-an lawon mejeeji, ti won je laami laka ninu ise sinima Yoruba ko ara won lo
si kootu, nibi ti won ti so won papo gege bi toko-taya.
Ni bayii, gbogbo eto lo
ti pari lori ayeye igbeyawo nla ti awon gbajumo onitiata yii fe se niluu Eko
lojo Abameta, Satide to n bo yii.
Ni kete ti
won ti so won papo gege bi toko-tiyawo alarede ni won ti kede e fawon eeyan wi
pe, ko tan sibe o, awon si maa dana ariya repete, ti gbogbo awon ololufe awon,
paapaa awon ti ko gbagbo yoo wa foju ara won ri i pe loooto ni Okiki Afolayan ti
di oko Bukola Ogunowo.
Adugbo kan ti won pe ni Adeniyi Jones n'Ikeja
l'Ekoo ni ayeye nla yii yoo ti waye.
Te o ba gbagbe, nigba die seyin ni awuyewuye gba igboro kan
wi pe awon mejeeji yii ni kinni kan ti won jo n se funra won ni koro yara. Bi hunrun-hunrun
oro yii se n lo nigboro ni Okiki ati iyawo e tuntun yii ko je ki awon eeyan
laagun jinna, tawon naa se bere si i gbe foto ara won sori ero ayelujara, ti
won si n ko orisirisi oro ife nipa ara won.
Bo tile je pe ariwo mi-in to tun gba igboro kan ni pe
obinrin naa ti bimo ri, ati pe omo odun marun-un kan wa lowo e, to bi fun
okunrin kan nigba kan ri, sibe Okiki Afolayan ti so pe, iyen ki i se babara, nitori
pe omo to ti bi ri yen gan-an lo fi obinrin naa han gege bi obinrin ti yoo
sabiyamo daadaa lodede oun.
Okan lara awon to maa n dari sinima Yoruba to loruko daadaa
lomokunrin yii n se, o si fe jo pe oun ni irawo e n tan daadaa ju lasiko yii ti
a ba n so nipa darekito fiimu Yoruba.
Bukola ni tie, osere tiata to munadoko ni, oun naa wa lara
awon arewa obinrin ti won n lo daadaa ninu awon sinima Yoruba lasiko yii.
Gbogbo bi eto igbeyawo yii ba se lo, le o maa ba pade ninu
Magasinni yii.
\
0 Comments