Nibi apero nla kan to waye ni gbongan Combo Hall nileese telifisan Eko, iyen LTV ni ipade apero ohun ti waye, ohun ti won si fi se koko oro ojo naa ni bi Aare Muhammed Buhari yoo se tun pada sori ipo leekan si i.
Nibi apero ohun lawon ololufee Aare Muhammed Buhari ti so pe ise nla ni okunrin naa n se, ati pe gbogbo kukukeke ti awon omo egbe oselu PDP da bole, won ni ofuutu-feete ni o, bee iyonu nla ni won yoo tun ko ba awon omo Nigeria leekan si i.
Okan lara awon eeyan pataki to soro lojo naa ni, Ogbeni Ife Adebayo, eni ti se oluranlowo fun igbakeji aare orile-ede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo. Ninu oro okunrin yii lo ti fidi e mule wi pe gbogbo eto eyawo ti ijoba Buhari n se pata, fun araalu ni o, ati pe ko sese digba ti eeyan ba ni baba ni igbejo tabi to ba je omo egbe oselu APC nikan ni yoo too le je anfaani nla ohun.
Siwaju si i, Ife Adebayo ti so pe, gbogbo eto tijoba ana so pe oun n se fun araalu, o ni iro patapata ni won pa, eyi ti ijoba Aare Muhammed Buhari fi yato si won.
E WO FIDIO TO WA LOKE YII LATI RI EKUNRERE OHUN TI IFE ADEBAYO SO
0 Comments