GBAJUMO

TAYE CURRENCY FE KORIN N’IPARA REMO *AYEYE OGUOLA DAY NI WON FE SE


Lati Fraide ojo kesan-an osun kokanla ni ayeye Ipara Remo Oguola Day todun 2018 yoo ti bere pelu oniruuru awon eto aladun, nibi ti gbajumo olorin fuji nni, Taye Currency yoo ti korin lojo Satide ojo ketadinlogun nigba ti won ba kadii eto ohun nile.
Ninu atejade ti awon igbimo eleto ohun, Ipara-Remo Committee of friends fi sowo si wa ni won ti fidi e mule wi pe Fraide leto ohun yoo bere, aago mokanla ni eto akoko yoo waye, eyi ti won pe ni Oguola Day Lecture ni gbongan nla Ipara Town Hall. Akori oro ti won yoo gbe yewo ni, Ipara lana-an, loni-in ati ojo iwaju e.
Bakan naa lojo yen, akanse adura yoo waye ni Mosalasi Jimo ilu Ipara Remo nibi ti won yoo ti gbadura fun gbogbo ilu naa, paapaa lori awon omo ilu ohun ti won wa nile atawon ti won wa leyin odi. Eto mi-in ti won yoo se lojo keji ni ipolongo ayeye pataki yii, bakan naa ni ere idaraya lorisirisi yoo tun waye, eto kole-kodoti lati satunse ayika ilu naa, bakan naa ni idije tun wa fawon ogo weere. Ayo olopon naa tun wa lara eto ti won ti la kale, bakan naa lawon ode yoo kopa ninu idije eran igbe dide laarin aago meje aaro si meje asale lojo Isegun Tusde ojo ketala.
Lojo kefa ti ayeye Oguola yii bere ni won yoo lu ilu gbedu yipo ilu naa laago mejo aaro, nigba ti akanse eto yoo waye ni deede aago merin irole, nibi ti won yoo ti  se etutu ninu ilu naa.
Lojo keje ti ayeye ohun ti bere ni won yoo seto ilera ofe fun tolori telemu ninu ilu naa, bakan naa ni awon egungun ilu naa yoo sere lorisirisi ni gbagede oja laago meji osan ojo naa, iyen ojo keedogun osu kokanla.

Lojo kejo, Fraide ojo kerindinlogun, lojo yen ni won yoo si iyara ikekoo ero komputa igbaloode ni deede aago mewaa aaro, nibi ti komisanna foro eko ati imo ijinle nipinle Ogun yoo ti si yara ikekoo ohun.
Siwaju si i, lojo yen naa ni idije tan mo on laarin awon omoleewe yoo waye, bakan naa ni idanilekoo fun awon ogo were laarin aago mokanla si aago kan osan, ti ere idaraya alafesegba yoo waye laago merin irole  ileewe United Pry School. Idije omidan naa yoo waye, bakan naa ni ajo CAN naa leto pataki ti won yoo se lojo naa.
Satide ojo ketadinlogun ni asekegba ayeye ohun yoo waye, nibi ti awon odo yoo ti dije, awon olokoda naa yoo fi irinse won dara, bee ni eto ikowojo oni ogorun-un milionu naira (N100Million) yoo waye. Bakan naa lawon eto mi-in yoo tele e, nibi ti Alhaji Taye Currency ati onifuji mi-in mi-in, Calipso fuji yoo ti forin aladun da awon eeyan laraya.
Lojo Sannde ni eto isin idupe yoo waye, bakan naa lawon Alagemo yoo se tiwon atawon eto mi-in lorisirisi fun asekagba.
Gomina ipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun ni alejo pataki ojo naa, nigba ti Amofin Asiwaju Bisi Adegbuyi je alaga ayeye pataki. Awon alejo pataki mi-in ti won tun n reti lojo naa ni Onarebu Segun Samuel Idowu, Oloye Funmi Awojebe, Oloye Taye Jowosinmi atawon eeyan pataki mi-in.
Awon igbimo eleto ti so pe, ayeye Ipara Remo Oguola todun yii ni yoo je eleekerindinlogbon (26th) ti won yoo se ninu ilu naa. Bakan naa ni won so pe, ti ote yii yoo yato nitori lodoodun lawon maa n fi ohun ara kun un, eyi to ti so ayeye ohun di pataki laarin awon omo ilu naa atawon ilu to yi i ka nipinle Ogun.
Siwaju si i, won ti so pe anakara ayeye naa wa lodo Moji Oniresi ni gareeji ilu naa, ati pe egberun kan aabo naira (N1,500) pere ni.

Post a Comment

0 Comments