Bi a ti se n ko iroyin yii, ilu
Abuja lohun-un ni Asiwaju Bola Tinubu wa, odo Aare Muhammed Buhari ni okunrin
oloselu yii lo, o si jo pe koko ohun to gbe e lo, oro to lagbara gidi gan an
ni.
Enikan to sunmo ofiisi aare ti
so pe, aago merin irole ni Tinubu ti ko sinu ofiisi aare kolo, gbaa-gbaa-gba ni
won si tilekun mori, ti awon eeyan ko ti i le so ohun ti won jo fe ba ara won
so.
Sa o, enikan ti gbe e si wa
leti wi pe, orisirisi wahala to n koju egbe naa lowo, latari eto idibo abele to
waye, nibi ti opo awon asofin ti won fe pada ko ti raaye mo, ati bi awon gomina
naa ko se ri eeyan won fa kale ninu eto idibo abele ni won fe jo so.
Abajade ipade ohun a o maa fi
to yin leti.
0 Comments