GBAJUMO

WON NI AISAN JEJERE LO PA AJIMAJASAN ONITIATA


Leyin ojo mokanla ti Moses Adejumo, eni tawon eeyan mo si Baba Sala ku, gbajumo nla nidii ise sinima mi-in, Ola Omonitan, iyen Ajimajasan naa ti jade laye o.
Loni-in, Ojobo niroyin ohun gba igboro kan wi pe gbajumo osere tiata naa ti ku leni ogorin odun (80).
Gege bi a se gbo, okan lara awon omo oloogbe ohun, iyen akobi e lobinrin, ti oruko e n je Ajike lo kede iku baba naa fun awon oniroyin. O ni, University College Hospital ni won gbe gbajumo osere tiata lo ni kete ti aisan kolu u, ati pe nibe ni won ti fidi e mule wi pe aisan okan  lo n da baba naa laamu atawon aisan orisi meji mi-in, opa eyin ati aisan jejere kan to saaba maa n mu awon okunrin, iyen prostate cancer.
Leyin ti Ajimajasan kuro ni osibitu to pade sile ni iku pa a loni-in ojo Tosde yii.
Sinima nla kan to se ti okiki e kan kaakiri, paapaa lori bo se je ere ori-itage olose metala lori telifisan, iyen Bata Wahala lo so o di gbajumo nla, tokiki e si gba igboro kan. Fiimu mi-in ti won tun mo mo on ni 'Omi Okun.'
Bi eto isinku e yoo se lo, a o maa fi to yin leti.

Post a Comment

0 Comments