GBAJUMO

ATIKU ABUBAKAR TI PADA SI NIGERIA *O NI KO SENI TO LE SERU BA OUN


Oludije fun ipo Aare loruko egbe oselu PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti bu enu ate lu bi awon eso agbofinro se yabo oun atawon eeyan e bi won se bale si orile-ede yii leyin ose meji ti won lo niluu Dubai lohun-un.
Lojo Aiku, iyen Sannde ana ni gbajumo oloselu yii pada si orile-ede yii. Bo ti se n de lawon eso alaabo ti won wa ni papako ofurufu Nnamdi Azikiwe international Airport ti yabo o, ti won n tu eru okunrin yii.
Lojuese, leyin to kuro lodo awon agbofinro yii loun naa ti gba ori eyo ayelujara re lo, iyen twitter, nibi to ti bu enu ate lu igbese ohun, to si sapejuwe igbese naa, gege bi eyi ti won lo lati fi maa dun mahuru-mahuru mo oun atawon alatileyin oun.
Ni kete ti Alhaji Atiku Abubakar ti gba tikeeti lati dije loruko egbe oselu PDP loun atawon iko e ti n sepade lorisirisi, ninu eyi ti won ti ko eru won, ti won si gba orile-ede United Emirate lo, iyen Dubai, nibi ti won ti lo sepade fodidi ose meji.
Ni kete ti won gba ilu ohun lo ni egbe oselu APC ti pariwo sita wi pe iru ipade wo ni won fe se ti won tori e ko eru soko gba Dubai lo. Bee ni won kesi eso agbofinro lati sewadii okurnin oloselu yii lori irin-ajo ohun.
 Sa o, Atiku Abubakar ti so pe, ohun to je oun logun ni bi oun yoo se mu itura ba awon omo Nigeria ni kete ti oun ba ti dori oye lodun 2019.

Post a Comment

0 Comments