Bi a se n soro yii, oke okun niluu oyinbo lohun-un ni Bunmi Akinnaanu wa
to fi ba Magasinni yii soro, ohun to si so ni pe ope ni oro oun ja si, ati pe
gbogbo awon ololufe oun loun dupe fun lori aduroti won.
Lara awon orile-ede to ni oun yoo de ki oun too pada si Nigeria ni Canada,
United Kingdom ati ilu Amerika to koko wole si ni kete to kuro ni Nigeria.
O fe je pe oke okun ni gbajumo olorin yii ti saaba maa n se ayajo ojoobi
e, nitori lohun-un naa lo ti se e lodun to koja.
Ni bayii, orisirisi atejise lo ti kun igboro foofo, tawon eeyan fi n ki i
ku oriire ojoobi e, bee loun naa ti seleri pe, ni kete ti oun ba pada si
Nigeria, ara otun loun n gbe bo fun igbadun awon ololufee oun lati fi se koriya
fun won.
Okan lara awon olorin emi to n se daadaa lasiko yii ni Bunmi Akinnaanu,
ni kete ti rekoodu Omije Oju mi to jade lodun naa lohu-un, eyi to mu okiki e
gba igboro kan ni irawo obinrin yii naa ti wa loke laala, tawon eeyan si n fe e
lotun ati losi, titi to fi de oke okun paapaa.
Latari akitiyan e nidii ise ohun, opolopo ami eye lo ti gba, eyi to fi i
han gege bi olorin nla kan, to laami-laka daadaa nidii orin emi.
Ninu oro e lo ti so pe, “Lojoojumo ni mo n dupe lowo Olorun lori aseyori
to n fun mi se, gbogbo ohun yoowu ti a le je tabi da nidii ise yii, Olorun oga
ogo lo se e, titi aye lemi yoo si maa polongo e, nitori ko si iru e, bee ni ko
ni i si laelae.”
O ti wa dupe lowo awon ololufe e, bee lo so pe, rekoodu Testimony ni won
ri ti won n so, eyi to n bo lona, orin emi tenikeni ko ti i gbo ri ni yoo je,
bee ni yoo je kokoro aseyori ati ipile ona abayo si ohunkohun to ba n koju eda,
nitori orin imisi ti yoo tu ide ja ide ni, ti Oluwa yoo si lo lati bu ororo itura
si ohunkohun to ba n yo eda lenu.”
0 Comments