GBAJUMO

EGBE ONIMOTO L’EKOO GBE BOOSI TUNTUN FUN BABAJIDE SANWO-OLU *WON LOUN GAN AN NI GBOGBO AWON N BA LO


Bi eto dibo odun to n bo se n sunmo etile, tawon oloselu ti bere ipolongo won, egbe onimoto nipinle Eko, iyen ‘National Union of Road Transport Workers’ (NURTW) labe alaga won, Alaaji Tajudeen Agbede, ti seleri atileyin nla fun oludije ipo gomina labe egbe oselu APC nipinle Eko, Ogbeni Babajide Olusola Sanwo-Olu tawon eeyan tun n pe ni Sanwo-Eko.
Alaaji Agbede ninu oro e so pe,  'Ti a ba wo o daadaa, a o ri i pe ninu gbogbo awon oludije ipo gomina nipinle Eko, Sanwo-Olu lo kunju osuwon lati se gomina. Oun ni yoo mu igbe-aye irorun ba gbogbo wa, ti yoo si mu ilosiwaju ati idagbasoke otun ba ipinle Eko.” 

Oga awon onimoto l’Ekoo yii ti wa ro awon egbe yooku ti won n sise oko wiwa l’Ekoo atawon mi-in bii egbe olokada; onikeke Maruwa lati satileyin to kunju osunwon fun Sanwo-Olu ki gbogbo ara Eko le je mudun-mudun ijoba gidi ti okunrin oloselu naa setan lati pese e fun ara Eko.
Siwaju si i, ninu oro adari gbogbogboo fun eto ipolongo ibo fun Sanwo-Olu,  Ogbeni Tayo Ayinde,  dupe lowo awon omo onimoto yii fun bi won se setan lati ti Sanwo-Olu leyin, paapaa lori bi won se gbe moto nla fun okunrin naa lati fi polongo ibo.

O ni, anfaani nla ni atileyin ti egbe onimoto yii se fun Sanwo-Olu je, bee lawon si mo riri ohun ti won se yii pelu. 
Bakan naa lo sapejuwe Alaaji Tajudeen Agbede gege bii asaaju gidi to ti mu ayipada rere ba ise moto nipinle Eko, eyi ti ko fi si wahala kankan ninu egbe naa mo.




Post a Comment

0 Comments