GBAJUMO

EMESI, ASOJU OGA NLA OLORIN FUJI FE DANA ARIYA REPETE L’EKOO *O TI NI PEPEYE YOO PON’MO


Bi popo-sinsin odun se n bo, tawon eeyan n mura fun ayeye lorisirisi, gbajumo olorin fuji nni, Musibau Adisa, eni tawon eeyan tun mo si Emesi Asoju Oga-nla ti pate ariya nla kan, to fe se ninu osu kejila odun yii.
Ninu atejade kan ti gbajumo olorin fuji to n migboro titi yii fi sowo si wa lo ti so pe, “O pe ti awa naa ti n ba a bo, ohun kan to se pataki fun eda to ba mo oore ni lati maa dupe fun Olorun ni gbogbo igba; ko si ka awon ololufe e ti won n gbe e laruage si.
“Adura ni mo maa fi n ran awon ololufe mi lowo ni gbogbo igba, nitori awon gan-an ni Olorun n lo fun mi, ti ohun gbogbo fi n dan, to n dun fun awa naa lagboole orin. Idi e niyi, ti a fe fi se akanse ariya fun gbogbo awon ololufe mi, nitori ojulowo eeyan ni gbogbo won pata n se.
“Awon ti won je tiwa la fe se e fun un o, ati gbogbo awon ololufe orin fuji patapata. Gbogbo eeyan la pe, e wa e je ki a jo yo, ka jo dupe lowo Olorun to so wa lati osu kin-in-ni, to si tun ti seleri lati so wa pari odun yii.”
Akole ayeye to fe se yii lo pe ni Emesy Fans Party 2018. Emesy ti so pe ojo kerindinlogun osu kejila ni ariya ohun yoo waye nileetura Goldlux Hotel, ni Ipaja road, Ile-Jide, bus stop, Agege, l’Ekoo
O ti so pe Ankara egbejoda lawon yoo fi sayeye ohun, eyi ti yoo waye laarin aago meji osan si mokanla asale. Bee lopo awon olorin fuji ti won je laami-laaka naa yoo wa nibe lojo naa lati ye oun atawon ololufe orin e si.  

Post a Comment

0 Comments